Kogi Assembly: Igbákejì gómìnà, Simon Achuba dèrò ilé lọ́jọ́ Ẹti

yahaya Bello Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Kogi Assembly: Igbákejì gómìnà, Simon Achuba dèrò ilé lọ́jọ́ Ẹti

Gomina ipinlẹ Kogi ni aarin gbungbun Naijiria ti kede Edwin Onoja to jẹ olori ile ijoba rẹ tẹlẹ gẹgẹ bii igbakeji rẹ tuntun tile ba fọwọ sii.

Yahaya Bello se ikede yii lẹyin ti awọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kogi ti yọ Simon Achuba lana pe ko lọ rọọkun nile Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Kogi júwe ilé fún ìgbákejì Gómìnà.

Edwin Onoja ni igbakeji ti gomina Yahaya Bello yan tẹlẹ bi igbakeji rẹ ninu idibo ipinlẹ Kogi to n bọ lọna loṣu to m bọ Yahaya Bello lẹ́ẹ̀kan síi ni APC ṣe ní ìdìbò abẹ́lé ní Kogi.

Ẹyin kọ lẹ yan mi sipo, ẹ ko le yọ mi nipo- Simon Achuba

Ṣaaju laarọ oni ni Simon Achuba ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kogi yọ nipo lọjọ Eti, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa ti sọ pe ọna ti wọn fi yọ oun ko tọna.

Amofin Jibrin Okutepa (SAN) to jẹ agbẹjọro Simon ni awọn ọmó ile igbimọ ko lo yan Simon sipo, ati pe agbara wọn ko to yọ onibara oun nipo.

O ni oun ṣi ni igbakeji gomina laisko yii nipinlẹ Kogi titi idajọ yoo fi waye lori igbẹjọ naa to ṣi wa nile ẹjọ.

Simon ni ile ẹjọ lo ṣi maa yanju ọrọ ipinlẹ Kogi.

Koda, Jibrin fidiẹ mulẹ pe Simon ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an nile igbimọ aṣofin rara.

Honọrebu Hassan Abdulahi to jẹ olori ile lo kede iyọkuro Simon ninu ile.

Hassan lo n ṣoju ẹkun Ajaokuta nile igbimọ aṣofin tipinlẹ Kogi.

Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla ni eto idibo lati yan gomina yoo waye nipinlẹ Kogi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdebisi Olabode: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti fòfin de oyè Ìyá àti Babalọja

Kini o ti ṣẹlẹ tẹlẹ?

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Kogi júwe ilé fún ìgbákejì Gómìnà

Igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Simon Achuba ti ṣaa dEede dero ile lọjọ Ẹti ọsẹ.

Ọgbẹni Achuba di ẹni ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kogi rọ loye lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa.

Image copyright OTHER

Ṣaaju igbesẹ yii ni iroyin ti tan kalẹ pe Ó ṣeéṣe kí ìpínlẹ̀ Kogi ní igbákejì gómìnà tuntun láìpẹ́.

Adari ẹgbẹ to pọ ju nile lo fọrọ̀ yii lede fun awọn oniroyin nita ile igbimọ aṣofin naa.

Ko pẹ ti ile aṣofin gba esi latọdọ igbimọ aṣewadii ti adajọ agba ipinlẹ Kogi, Nasir Ajanah gbe kalẹ ni wọn gbe igbesẹ naa.

Aṣofin Hassan Bello Abdullahi ni gbogbo aṣofin ile lo pawọpọ fọwọ si esi igbimọ aṣewadii naa ti wn si rọ igbakeji gomina loye.

Adari ile, Mathew Kolawole tẹwọ gba abọ iwadii lọjọ Ẹti lẹyin rẹ si ni gbogbo ọmọ ile wọnu ipade atilẹkun mọri ṣe lati jiroro lori ohun to wa ninu abọ naa.

Igbimọ aṣewadii ka ẹsun ṣiṣe mọku mọku mọ igbakeji gomina lẹsẹ.

Ṣaaju ni Achuba ti fi ẹsun kan gomina Yahaya Bello pe o ha owo oṣu oun ati owo fun iṣẹ ṣiṣe m'ọwọ lati ọdun 2017.

Ṣugbọn ijọba ipinlẹ naa bu ẹnu atẹ lu ẹsun rẹ niwaju igbim aṣewadii pe kii ṣe ootọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPainter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!