Toyin Abraham ní òun lo àgbo ni ipo iloyun

Oṣere Toyin Abraham Image copyright toyin_abraham
Àkọlé àwòrán Toyin Abraham ní òun lo àgbo ni ipo iloyun

Gbajúgbajà òṣèré Yorùbá, Toyin Abraham sọ ìtàn bí ò ṣe di abiyamọ láìpẹ́ yìí lásìkò tó bẹ̀rẹ̀ ìpolówó ọjà rẹ̀ to ṣẹṣẹ dawọ le.

Toyin to ṣẹṣẹ bẹrẹ owo tita awọn ewe ati egboogi ibilẹ ni ilana igbalode ni oun n sọ itan b'oun ṣe di abiyamọ lati le jẹ ọna ibukun fun ọpọlọpọ.

Laipẹ yii, ija suyọ laarin oun ati akẹgbẹ rẹ ninu sinima Yoruba, Lizzy Anjorin lasiko ti Toyin Abraham sọkalẹ ayọ ọmọ tuntun, aawọ yii si hu ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ sita.

Toyin Abraham ni o ti jẹ ohun to wu oun lọkan lati di abiyamọ, o si dupẹ pupọ pe Ọlọrun wa fun un ni "Ire" tirẹ.

Aya Kolawole jẹ ko di mimọ pe ọpọ obinrin bii toun naa lo n reti ati di iya aburo ti wọn si ti la oniruuru iriri kọja nipa iloyun "nitori naa ni mo ṣe n fi ohun to ṣiṣẹ fun mi han fun un yin - Itọju pẹlu egboogi".

Toyin ni pẹlu iranlọwọ awọn oniṣegun ibilẹ to moye ni oun fi mọ ara ti awọn ewe ati egboogi ibilẹ n da eyi ti o si mu lo.