Adebisi Olabode: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti fòfin de oyè Ìyá àti Babalọja

Ọrọ oyè kò yẹ ko mu ija nla bayii dani- Kọmiṣọnna

Ṣaaju asiko yii ni awuyewuye ti waye kaakiri ọja ipinlẹ Oyo lori tani iyalọja ati babalọja fun ipinlẹ Oyo lapapọ?.

Lẹyin gbogbo awuyewuye yii ni ijoba ipinlẹ Oyo labẹ akoso Gomina Seyi Makinde ti fofin de oye naa ni ipinle Oyo

BBC Yoruba gbera lọ fọrọ wa awọn ti ọrọ kan lẹnuwo lati mọ ohun to n ṣẹlẹ lori ọrọ Iyalọja ati Babalọja ipinlẹ Oyo yii.

Kọmiṣọnna feto idokowo nipinlẹ Oyo, Adebisi Adeniyi Olabode ṣalaye ohun to ṣokunfa awuyewuye yii fun BBC.

O mẹnuba igbesẹ ijọba ipinlẹ Oyo ki alaafia le jọba lawọn ọja ati ki ijọba fi raaye ṣe iwadii to yẹ lori iṣẹlẹ yii.

Bakan naa ni BBC ba iyalọja ilẹ Ibadan, Alhaja Iswat Abiola Amerigun naa ba BBC sọrọ lori iṣẹlẹ yii.

Kọmiṣọna ni kete ti iwadii ijọba ba ti pari ni wọn yoo gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ yii.

Gbogbo igbiyanju BBC lati ba awọn igun to ku to n ja sọrọ oye yii sọrọ lo ja si pabo lasiko yii.