Ondo Accident: Agbègbè Awoyaya ní gáréjì Ifẹ l‘ondo ní ìjàǹbá náà ti wáyé

Ondo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ náà wáyé ní aago mẹ́rin àárò èyí tó mú ẹ̀mí ènìyàn márùn ún lọ, tí ènìyàn méjì sì farapa.

Ijamba ọkọ ayọkẹlẹ ati ọkọ tirela ni ipinlẹ Ondo ti mu ẹmi eniyan marun un lọ, ti eniyan meji si farapa.

Agbẹnusọ fun ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Femi Joseph to fi idi ọrọ naa mulẹ, ni isẹlẹ naa waye ni agbegbe Awoyaya, ni gareji Ife ni ilu Ondo.

Iroyin naa fikun pe, awọn mẹjọ ni wọn wa ni inu ọkọ Sharon Volkswagen ti eniyan marun pẹlu awakọ ku, amọ wọn ko mọ ibi ti eniyan yoku wa.

Wẹrẹ ti isẹlẹ naa sẹlẹ ni awakọ tirela naa ti fẹsẹ fẹ, amọ ti ọlọpaa ni wọn n wa a lọwọ.

Bakan naa ni wọn fikun wi pe, wọn ti gbe awọn to ku naa lọ si ile igbokusi to wa ni ilu Ondo.