Traffic Robbery: Àwọ́n ìgbésẹ̀ tó tọ́ fún ọ láti tẹ̀lé nínú súnkẹrẹ ojú pópó

Sunkerke fakere ọkọ
Àkọlé àwòrán Àwọn ọ̀nà láti bọ́ lọ́wọ́ olè nínú súkẹrẹ fakẹrẹ ojú pópó

Ìwà ọ̀dáran ní àwọn ìlú ńlá ńlá ti ń peléke síi pàápàá júlọ nínú súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ lóju pópó ní ìpínlẹ̀ Eko àti lórílẹ̀-èdè Nàijíríà lápapọ̀.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ti àwọn ènìyàn bá há sínú súnkẹrẹ fákẹrẹ lóju pópó ni àwọn oniṣẹ́ laabi náà a fi ànfani bẹ́ẹ̀ láti jale ǹkan ini àwọn ènìyàn to da látori fóónù, owó àti àwọn ǹkan ini míràn to fi mọ jíjí ọkọ wọ́n gbé.

Ẹ̀wẹ̀, ojú ni alákan fi n sori ni ọ̀rọ náà wá dá báyìí ni BBC Yoruba ṣe ṣe iwadii àwọn ọ̀nà àbáyọ ti ènìyàn le gba láti dẹ́kun ìrú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀.

Ní àkọkọ tí o ba ti ríi pé ilẹ̀ ti fẹ bẹ̀rẹ̀ sinii ṣu, ti o ko si i ni nínú ilé rẹ̀, o ṣe pàtàki láti kúrò nibikibi to o wa láti maa lọ si ilé.

Nípa eléyìí, o ṣeeṣe ki o ma bọ sínu súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ, nítori pé ìjáfara léwu ni ọ̀rọ ojú pópó ìpinlẹ Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHelgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil

Yálà o jẹ́ ọkúnrin tàbi obinrin, o ṣe pàtàkì láti yọ gbogbo ẹgbà ọrùn àti ọwọ́ kúrò ni àsìkò ti o ba ti ba sínú súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ paapa ti wọn ba jẹ goolu tabi olowo nla.

Bakan naa lo ṣe pàtàkì láti ma kóò sínú àpamọwọ rẹ̀ nítori pé o ṣeeṣe kí wọn beere fun ìpamọwọ rẹ, nítori náà o gbọdọ fi pamọ sinu ọkọ ni.

Kí o to jáde kúrò ninú ọkọ ti a ba gbekalẹ, rìí dáju pé àwọn ǹkan tó sẹ pàtàki sí ọ kò sí ní ibi ti ojú ará ita ti le tàn síì; kó wọ́n pámọ si abẹ́ aga inú ọkọ, ṣe akíyesi yìí dárádára láti ri i dáju pe ará ita ko ríi.

Tí o ba ti fi owó díẹ̀ sínú àpamọwọ́ rẹ̀, kó èyí to kú pamọ kúro ni àrọ́wọ́to, o le ko wọn pamọ sí ibi kan ninú mọtò, má fi ohunkohun sínu apo asọ ti o wọ.

Àkọlé àwòrán Ọga ọlọpaa kan ni o ṣe pàtàki láti fọ́wọ́ sowọpọ̀ pẹ̀lú àwọn ajínígbé làsìkò to ba fi wà lábẹ́ àkóso wọ̀n.

Gbara ti o ba ti ri súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ fá gbogbo gílààsi ọkọ rẹ soke ki o si ti ara rẹ pa mọ inu ọkọ, ti o ba wá pọ́ndandan fún ọ láti gba atẹgun sára ma fa gílaàsi rẹ wálẹ jú ìwọ́n méji lọ.

Bí ẹnikẹni ba wa kan ọkọ rẹ̀, máṣe ṣí ìlẹkun tàbi fa gílààsì rẹ wálẹ, kàkà bẹ́ẹ̀ ti o ba dẹ́ruba ọ bẹrẹ si ni fi ọkọ rẹ han ki ojú gbogbo ènìyàn le wá si apá ibi ti o wà, èyí yóò si mú ki iru ọdaràn náà sa nitori pe ọ̀pọ̀ ọdaran maa n bẹ̀ru ki wọ́n ma gba oun mú.

Gbìyànju lati maa mu fóònù ti ko dárámọ dáni ki foonu ti ẹ to dara si maa wa ni ìdákẹ rọ́rọ́ nígbà gbogbo ki o si wà lọ́bẹ ìjókó rẹ̀ ninu mọto.

Èyí to tun ṣe pàtàki jùlọ ni ki o maa mú ẹ̀dà kọ́kọ́rọ mọto rẹ dáni ni gbogbo ìgbà nitori àwọn ole a maa gba kọ́kọ́rọ́ mọto lati wa gbe pada gbee ti sunkẹrẹ fakẹrẹ ba ti bíyá.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìgbésẹ̀ Marùn tí o lè gbé lati bóyọ lọ́wa Ajinigbé.

Ìgbésẹ̀ márùn-ún tí o lè gbé lati bọ́ láàyè lọ́wọ́ Ajinigbé

Ọ̀rọ̀ ìjínígbé kìí ṣe ohun tuntun mọ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lai naani ipò kípò tí o bá wa, kò si ẹni ti kò le bọ si ọwọ àwọn ajínígbé.

Laipẹ ni wọ́n tún ji igbákeji kọmísọna ọlọpàá àti oludari ileesẹ ọlọpa lẹkun Suleja, Musa Rabo, gbe ni òpópónà Barde si Jos.

Bo tilẹ jẹ́ pé ilé iṣẹ́ ọlọpàá ni àwọn ti rí àwọn méjeèjì ti wọn jí gbe pàda, ti àwọn si ti mú àwọn ajínígbé náà, sugbọn isẹlẹ fíhàn pé, kò si ẹni ti kò le kó si pànpẹ́ ajinigbe.

Nítori àwọn ìsẹlẹ̀ yìí ni BBC fi ṣe ìwádìí lọwọ ọga ọlọpa kan nipa àwọn ìgbésẹ̀ ti èniyan le gbé, láti ri ìtúsílẹ̀ laaye, to bá tilẹ̀ bọ si ọwọ àjínigbe.

Image copyright @okasanmi
Àkọlé àwòrán Ìgbésẹ̀ Marùn tí o lè gbé lati bóyọ lọ́wa Ajinigbé.

Ọ̀nà márùn-un tí o lé fi bọ́ lọ́wọ́ ajinigbe:

Gẹ́gẹ́ bi àgbẹnusọ ọlọpàá ìpínlẹ̀ Kwara, Ajayi Okasanmi se sọ, o ní bi àjínígbé ba kọ́kọ́ mú énìyàn, awọn ohun to yẹ ka ṣe ree.

  • Ohun àkọkọ to ṣe pàtàkì ni pé, gbà nínú ara rẹ pé lóòtọ́ ni o ti bọ si ọ́wọ́ ajínigbe, nítori náà, kíké àbámọ tàbi dída ẹ̀bi ru ẹnikẹni ko lè wáyé mọ, èyí yóò si fún iru ẹni bẹ́ẹ̀ ní ànfani láti tètè mọ ọ̀nà abáyọ
  • Ìgbésẹ̀ keji ni láti to gbogbo èrò rẹ̀ papọ láti mọ bí ò ṣe ronu lórí ǹkan ti wọn ba ń bèèrè, nítori pé ní orílẹ̀-èdè Naijiria, ọ̀pọ̀ ìjínigbé kò ju tori owo lọ, nítori náà, ti ẹnikẹ́ni ba ti bọ si ọwọ àjinigbe, o gbọdọ mọ àlude àti apade ọ̀rọ̀ rẹ, kò gbọdọ tàse, ko maa ba la ikú lọ kí ìrànlọ́wọ́ to de.

Yinka Quadri: Mo dúpẹ́ pé Ogogo jẹ́ ọ̀rẹ́ mi!

Soyombo yẹ fún àyẹ́sí gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagì oníròyìn - Aregbesola

Àwọn Ìyá àwọn ọmọ Yahoo ti ń kórajọ láti dá ẹgbẹ́ sílẹ̀ - Magu

Eni bá lu ayálégbé ní jìbìtì L'Eko yóò ṣẹ̀wọ̀n - Ijọba

  • Lẹ́yìn èyí, ó ṣe pàtàkì fún ẹni ti wọn ji gbé láti mọ pé oun ko gbọdọ fi oju rinju pẹ̀lú ajínigbe, ìdí èyí ni pé, ó ṣeeṣe ki ọkàn nínú àwọn ajínígbe jẹ ẹni mímọ̀, ti oju wọn ba wá pade pẹlu irú ènìyàn bàyìí, o lé la ẹmi lọ
  • O ṣe pàtàki láti fọ́wọ́ sowọpọ̀ pẹ̀lú àwọn ajínígbé ní àsìkò ti o ba fi wà lábẹ́ àkóso wọ̀n, wan kìí ṣe ẹni ti ẹniyan le ba jiyaǹ, o ṣe pataki láti dáhun gbogbo ibere ti wọ́n ba n bere, lati ori Number ipe, tabi ti ATM to fi mọ àdírẹ̀ẹ̀sì.

Afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná bú gbàmù! Ẹ̀mí èèyàn 74 ṣòfò nílùú Karachi

Kò burú bí Twitter bá fòfin dè ìpolongo òṣèlú lójú òpó - Kayode Ogundamisi

Kíni àwọn ohun tó yẹ kí ẹ mọ̀ nipa àjọ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀?

Àṣírí pásìtọ̀ tó ń fí sọ́ọ̀si ṣe ọ̀gbà wèrè tú!

  • Bákan náà lo tun ṣe pàtàki láti ni ìgbòya, èyi ni okun inu ti yóò ma sọ fun ẹni náà pe yoo làájá, bi iru igboya yìí ba si ti wà, ẹni náa yoo le gbágbọ pe oun yoo ri itúsilẹ̀ ati pe ìrànlọ́wọ́ ń bọ, nínú gbogbo ìsòrò yìí àdúra sẹ pàtàki àti 'pé o gbọ̀dọ̀ bawọn dọrẹ, èyí yóò jẹ ki àwọn ajinigbe yii náà mọ pe àye rẹ o lé àti pe gbogbo ǹkan ti o ń ba àwọn sọ ni òòtọ́ wà nibẹ̀.

Ọkasanmi wá gba ọmọ Nàìjíríà níyànju pé, ó ṣe pàtàki láti wá gbogbo ọ̀nà láti maṣe bọ sọ́wọ́ àwọn ajínígbe, pàápàá jùlọ, nitori pe ìgbé aye ẹlomiran lori ẹ̀rọ ayelujara lo sokùnfa bi wọ́n ṣe n ji wọn gbe.

Zanku tó gbòde kan, wo ìtumọ̀ àti bó ṣe bá orin tuntun Zlatan mu

Mobolaji Johnson: Kíkọ́ Eko Bridge, wíwó ibojì òkú Ajẹlẹ àti àwọn mánigbàgbé míì tó ṣe l'Eko

Nínú ká máa rin ìrìnàjò ilẹ̀ òkèèrè, ọgá ní Ọbasanjọ jẹ́ fún Buhari- Oshiomole

Ọmọ Nàìjíríà ló lè sọ bó yá ìdájọ́ òdodo nilé ẹjọ́ dá- Atiku Abubakar