Naira Marley: Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Naira Marley lórí ẹ̀sún jìbìtì

Naira Marley nile ẹjọ Image copyright @officialEFCC
Àkọlé àwòrán Naira Marley sọ fun ile ẹjọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsunti EFCC fi kan oun

Ile ẹjọ giga kan nilu Eko ti sun igbejọ Azzez Fashola, ti apele rẹ n jẹ Naira Maley, si ọla ode yii.

Ṣaaju ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC ti fi ẹsun kan Naira Maley lori ọrọ to jọ mọ lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara.

Adajọ to n gbọ ẹjọ naa, Nicholas Oweibo pinnu lati sun ẹjọ ọhun siwaju lẹyin ti agbẹjọro fun olujẹjọ, Olalekan Ojo, rọ ile ẹjọ naa lati kan an nipa fun EFCC lati pese afikun iwe ẹri lori afurasi naa.

Ogunjọ oṣu karun un ọdun yii ni EFCC kọkọ gbe Naira marley lọ sile ẹjọ, ti wọn si fi ẹsun mọkanla kan an.

Ṣugbọn afurasi naa ti sọ fun ile ẹjọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti EFCC fi kan oun.

Lẹyin atotonu agbẹjọro EFCC ati agbẹjọro fun Naira Marley ni ile ẹjọ sun igbẹjọ naa di ọjọ kẹtalelogun ọṣu yii, ti ṣe ọla ode yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKengbe Ilorin: Àṣà ẹ̀yà Fulani, Bariba àti Gambari tó dàpọ̀ mọ́ ti Yoruba