EFCC: Pàṣípáàrọ̀ owó ni Mompha fi ń bojú láti ṣe gbájúẹ̀ àti 419

EFCC Image copyright Instagram
Àkọlé àwòrán Orí ẹ̀rọ ayélujára ń gbóná lala láti ìgbà tí ọwọ́ sìnkú àjọ EFCC ti tẹ Ismaila Mustapha tí wọ́n ń pè ní Mompha.

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, ti sọ idi ti awọn fi mu gbajugbaja olowo ori Instagram, Ismaila Mustapha ti wọn n pe ni Mompha.

Ajọ EFCC lori Twitter ni wọn ti salaye pe, ẹsun gbajuẹ, ole jija lori ẹrọ ayelujara ni wọn fi kan ọdọmọkunrin naa.

Mompha ti wọn fẹsun kan naa, lo ma n gbe igbe aye olowo pẹlu bii o se ma n fi aworan owo ilẹ okeere si ori ikanni Instagram rẹ, ati adura ni ọpọ igba.

Bobrisky lori Instagram ni oun ko gba ẹsun ti wọn fi kan Mompha gbọ, nitori oninure ni ọdọmọde olowo Instagram naa.

EFCC ni isẹ pipaarọ owo Naijiria si tilẹ okeere ni Mompha fi n boju lati fi se isẹ gbajuẹ ati 419 ti wọn fi kan an.

Papakọ ofurufu ti Nmandi Azikwe ni ipinlẹ Eko ni Ajọ EFCC ni awọn ti mu Mompha, lẹyin ti ile isẹ ọlọpaa ilẹ okeere Interpol tawọn lolobo nipa igbe aye Mompha.

Image copyright TWITTER

Ni bayii, EFCC ni Mompha ti jẹwọ wi pe lootọ ni oun se gbajuẹ ẹsun meji ninu mẹrin ti wọn fi kan an, ti wọn si ba aago ọwọ marun un lọwọ rẹ, ti iye rẹ si jẹ ogun miliọnu Naira (N20,000,000.00).

Image copyright TWITTER

Ajọ EFCC ni awọn yoo gbe Mompha lọ si ile ẹjọ, lẹyin ti wọn ba pari iwadii wọn.