NLC: A ó gbé ìpínlẹ̀ tí kò bá san ₦30,000 owó osù tuntun lọ sílé ẹjọ́

NLC Image copyright TWITTER
Àkọlé àwòrán Àjọ Òsìsẹ́ lórílẹ̀èdé Naijiria, NLC ti ní àwọn yóò gbé ìjọba ìpínlẹ̀ tó bá kọ̀ láti san 30,000 gbèdéke owó osù òsìsẹ́.

Ijọba ipinlẹ Ondo, Ọyọ ati Kwara ti sọ wi pe, awọn ko le e sọ lọwọlọwọ bayii boya awọn yoo san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira (₦30,000) gẹgẹ bi owo osu tuntun fawọn osisẹ eyi tijọba apapọ sẹsẹ fẹnu rẹ jona.

Eyi ko sẹyin bi Apapọ ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria, NLC ti ni awọn yoo gbe ijọba ipinlẹ to ba kọ lati san gbedeke owo osu tuntun lọ sile ẹjọ.

Ondo, Oyo, Kwara lori gbedeke 30,000 owo osu osisẹ

Komisona feto iroyin ni ipinlẹ Ondo, Donald Ojogo, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe, ijọba ipinlẹ Ondo ti gbe igbimọ kan kalẹ lati se ayẹwo awọn osisẹ to wa ni ipinlẹ Ondo, boya awọn yoo le san owo osu tuntun fawọn osisẹ naa.

Image copyright Twitter

Ninu ọrọ tiẹ, Komisona fun eto iroyin ni ipinlẹ Oyo, Wasiu Olatunbosun ni, ijọba ko le e sọ pato igba ti awọn yoo bẹrẹ si ni san owo osu osisẹ tuntun.

Olatunbosun fikun pe, awọn yoo se ipade lati se ayẹwo ohun to wa nilẹ, ki awọn to le e sọ pe awọn yoo san gbedeke owo osu osisẹ ni ipinlẹ Oyo.

Bakan naa, Oluranlọwọ fun Gomina Ipinlẹ Kwara fọrọ iroyin, Rafiu Ajakaye ti ni asọyepọ gbọdọ waye laarin ijọba ipinlẹ ati awọn osisẹ, ki awọn to le e gbe igbesẹ kankan lori sisan owo osu osisẹ tuntun.

Ajakaye tun fikun wi pe ,awọ̀n ko mọ igba tabi akoko ti ipade laarin ijọba ati osisẹ yoo waye, amọ laipẹ awọn yoo sọ ipinnu wọn lori ọrọ naa.

Ipinlẹ Eko ati Ekiti gba lati san 30,000 owo osu osisẹ

Amọ ijọba ipinlẹ Eko ati Ekiti ti sọ wi pe, awọn yoo san gbedeke owo osu osisẹ.

Ti a ko ba gbagbe, ijọba apapọ ti gba lati bẹrẹ si ni san ẹgbẹrun lọna ọgbọn (30,000) gẹgẹ bi gbedeke owo osu tuntun fawọn osisẹ Naijiria.