Ìjàmbá Eko: Ṣúnkẹrẹ fàkẹrẹ gba òpópónà Berger kan torí ìjàmbá ọkọ̀

Ijamba Afara Otedola

Iye eeyan to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ to waye lori afara Otedola lopopona Eko si Ibadan ko tii hande.

ijamba naa ṣẹlẹ lowurọ Ọjọru ọsẹ ninu eyi ti ọkọ agbepo kan ati ọpọlọpọ ọkọ akẹru atawọn ọkọ mii wa.

Lati owurọ ni ijamba naa ti fa ọpọlọpọ sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ loju popo ni iha kinni ati iha keji ọna gan ti ijamba ko ti ṣẹlẹ tori ọpọlọpọ awakọ to n lọ lo dara duro lati woran.

Koda awọn arinrinajo to n lọ ọna jinjin ko lee ṣi kuro loju kan tori ijamba yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bo tilẹ jẹ wi pe ẹkunrẹrẹ iroyin ko tii si nipa ijamba yii, ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko (LASMA) fi ọpọlọpọ ọrọ sita nipa rẹ, loju opo Twitter wọn.

Awọn oṣiṣẹ pajawiri ni awọn ti ko awọn ọkọ to wa loju ọna kuro bayii.

Ṣaaju, LASTMA gba awọn awakọ nimọran lati lọ gba awọn ọna abuda mii lọ si ibi ti wọn ba n lọ kawọn oṣiṣẹ le doola awọn to fara gba ati ki ọna le la.