Yoruba film: Ipò wo ni Seun Egbegbe, Olóòtú eré wà báyìí lẹ́wọ̀n?

Seun Egbegbe Image copyright Instagram
Àkọlé àwòrán Seun Egbegbe lo ọdún méjì àti oṣù méje lẹ́wọ̀n láì tìí san béèlì rẹ̀

Olootu ere laarin awọn oṣere Yoruba, Olajide Kareem ti gbogbo eeyan mọ si Seun Egbegbe ti lo o le lọdun meji ati abọ lọgba ẹwọn bayii.

Koi tii lee san beeli owo miliọnu marun un ti ile ẹjọ giga wọ̀n fun un niluu Eko.

Ẹni ọdun mẹtalelogoji ni Egbegbe ti ọwọ ofin tẹ lori ẹsun pe o fi ọna eru gba owo lọwọ awọn to n ṣe pasiparọ owo ti ko din ni ogoji kaakiri ilu Eko.

Iroyin sọ pe ṣe ni Egbegbe a tan wọn pẹlu ko sọ fun wọn pe oun ni owo Naira ti oun fẹ parọ si ti ilẹ okeere tabi ti ile okeere si Naira ni yoo ba lọ wọn lọwọ gba.

Bakan naa wọn tun fi ẹsun pe wọn ba ọpọlọpọ ẹrọ ibanisọrọ iphone to ji lọwọ rẹ.

Eyi lo mu ki wọn gbe e janto lọ si ile ẹjọ to si ba ara rẹ lọ́gbà ẹwọ́n lati ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2017.

Oniruuru ni awọn ẹsun ti wọn fi kan olootu ere Yoruba yii to jẹ ẹni mimọ daadaa niluu Eko, ẹsun latorii owo Naira N39,098,100, si owo dollar $90,000 ati Pounds £12,550.

Image copyright Instagram

Egbegbe pẹlu ẹnikan to n jẹ Oyekan Ayomide ni wọn mu lọdun 2017 ti wọn farahan niwaju adajọ agba Oluremi Oguntoyinbo lori ẹsun mẹrindinlogoji to ni i ṣe pẹlu owo ko to di pe ọwọ tẹ awọn mii ti ẹsun pa wọn pọ.

Olootu ere Yoruba yii ti fi igba kan ri jẹ ọkọ afẹsọna gbajugbaja oṣere, Toyin Abraham.

Awọn afurasi ọdaran naa ni awọn ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan wọn ṣugbọn wọn ṣi wa latimọle di akoko yii.

Lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2017 kan naa ni adajọ agba Oguntoyinbo dajọ pe wọn yoo san beeli miliọnu marun un naira pẹlu oniduro meji.

Ni adajọ agba ba pa a laṣẹ pe ki wọn wa ni atimọle titi di igba ti wọ́n ba lee san beeli wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMama Rainbow: Toyin Adegbola àti Razak Olayiwola ní ìyá rere àti àwòkọ́ṣe gidi ní

O ti wa pe ọdun meji ati oṣu meje bayii ti Egbegbe lo lẹwọn Ikoyi niluu Eko ṣugbọn ti ko tii ri alagbaalẹ kankan ninu ẹbi tabi ara ti yoo gba beeli rẹ.

Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni "kii ṣe ẹbi wa pe o ṣi wa lẹwọn, tori ko ri ẹnikẹni gba beeli rẹ ni".

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Independence Day: Wo ìlérí tí àwọn ènìyàn ṣe