Mo sá kúrò nílé tí mo yá mílíọ̀nù 17 kọ́ ní Àkútè- Bayo Okeowo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ogun flood: ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé agbegbe yii ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí wọn kò lè jáde

Omiyale ati agbara ya ṣọọbu sọ awọn eniyan ipinlẹ Ogun di alinilelori.

Ọrọ omiyale, agbara ya ṣọọbu ti wa n gba ẹbọ lọwọ awọn eniyan Naijiria bayii.

Lasiko yii, awọn eniyan Iṣaṣi, Denro, Akute, Ibọkọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni omiyale ti le kuro ninu ile wọn ti ọpọ si ti padanu iṣẹ rẹ nitori pe wọn ko le jade.

Ogbeni Bayo Okeowo to jẹ ọkan lara awọn to n gbe agbegbe yii sọ ohun ti oju rẹ ri lẹyin to fi ọpọlọpọ owo oniru, owo oniyọ kọ ile nibẹ.

Sugbọn ti ẹkun omi yii si ti sọọ di ayalegbe bayii.

Funmilayọ Ọrẹtuyi to tun n gbe ibẹ naa sọrọ pe omiyale yii ko jẹ ki oun jade nile mọ ati pe awọn miran ni owo atijade nile ti wọn sii.

Eyi waye nitori pe ọwọngogo owo ọkọ ti pọju nitori ẹkun omi to ti gba gbogbo oju titi tan.