Naira Marley: Àwọn agbẹjọ́rò ń jà sí àga ìjókòó níbi ìgbẹ́jọ́ Naira Marley

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, nairamarley

Ile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Eko ti sun igbẹjọ gbajugbaja olorin Afeez Fashola ti gbogbo eniyan mọ si Naira Marley.

Gbajugbaja olorin Afeez Fashola ti gbogbo eniyan mọ si Naira Marley ti papa fara han niwaju ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Eko lori ẹsun ṣiṣe magomago lori ayelujara.

Ṣaaju ni iroyin jade pe yoo fara han niwaju ile ẹjọ lọjọru ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹwa ọdun 2019.

Lọjọbọ ẹwẹ, ṣaadede ni igbẹjọ olorin naa wa sopin gẹgẹ bi iroyin ṣe ni aigbọraẹniye dede suyọ laarin awọn agbẹjọro lori aaye atijoko ninu ile ẹjọ kekere naa.

Adajọ to dari igbẹjọ naa, Nicholas Owibo ni lati sun igbẹjọ rẹ siwaju di ọjọ ikọkanla ati ikejila oṣu ikejila ọdun 2019 tori aawọ to waye laarin agbẹjọro.

A gbọ pe aigbọraẹniye yii waye tori ile ẹjọ kii fibẹẹ tobi.

Ninu oṣu karun ọdun 2019 ni ajọ to n ri si iwa jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria, EFCC gbe Naira Marley atawọn mẹrin mii, Zlatan Ibile, Rahmon Jago, Guccy Branch ati eeyan kan.

Lẹyin ọjọ marun ni wọn tu Zlatan atawọn mẹta toku silẹ ti wọn si fi ẹsun mọkanla ọtọọtọ kan Naira Marley.

Nigba to ya ni iroyin tun jade pe ẹsun rẹ gangan ni to ni ṣe pẹlu ọpọlọpọ kaadi ipe lori ẹrọ ayelujara.

Àkọlé fídíò,

Ogun flood: ọ̀ps àwọn olùgbé agbegbe yii ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí wọn kò lè jáde