Ilorin illegal Rehab: Bàbá ẹni ọdún 77 ni alákòóso ibùdó

Ibudo atunwaṣe ni Ilorin

Oríṣun àwòrán, OTHER

Ile iṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Kwara ni igbesẹ tawọn n gbe lọwọ ni lati wa ọna ati mọ awọn obi awọn eeyan ọgọrun o le mẹjọ ti wọn ko si ayederu ibudo atunwaṣe ni Ilorin.

Lẹyin eyi, ijọba ipinlẹ Kwara naa ti ṣeleri lati ko awọn ti alafia wọn ba ku diẹ kaato lọ fun iwosan to peye.

Nigba ti BBC Yoruba kan si alukoro ile iṣẹ Ọlọpaa Kwara, Ajayi Okasanmi Jeffrey sọ pe awọn yoo ko awọn tara wọn ya fun awọn obi wọn.

O ni awọn kan o tilẹ ni obi mọ tori wọn ti pẹ nibẹ gẹgẹ bi baba agbalagba to ni ile naa ṣe sọ pe obi lo ko gbogbo wọn wa. "Ohun to ba tọ si baba yii la o ṣe fun un gẹgẹ bi obi.

"A ti fẹẹ to laarin ọgbọn si ogoji obi ti a ti kan si bayii. Pupọ ninu wọn lo ni funra awọn lawn gbe wọn lọ sibẹ tori wọn jẹ alaigbọran tabi ole, onipanle ọmọ ti wọn si fẹ ki wọn lọ kọ keu".

Ajayi sọ pe awọn obi ko le mọ nipa iru iya to n jẹ awọn ọmọ yii tori wọn ko wọ ibẹ. Bi awọn ti wọn ko nigbekun ṣe ni ko sẹni to wa wo wọn wo ni baba ni awọn obi n wa.

Oríṣun àwòrán, Yinka Alaya/Facebook

Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara fi panpẹ ofin mu ibudo atúnwàṣe yii ti wọn ti ko eniyan ọgọrun o le mẹjọ sigbekun lọna aitọ ni agbegbe Ọlọrunṣogo, Ilorin, ipinlẹ Kwara.

Ọkunrin ọgọrun le mẹta lo wa ni ahamọ yii ati obinrin marun un ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mejila si ogoji ti wọn si de ọpọ wọn nigbekun.

Iroyin sọ pe irisi awọn to wa lahamọ yii jọ ti awọn ti ko ri itọju rara ti ko si rounjẹ jẹ fun ọpọlọpọ ọjọ.

Bi o tilẹ jẹ pe lara awọn to wa ninu igbekun ti ọlọpaa ti gba silẹ ni lootọ ni awọn ya ọmọ buruku to si jẹ pe latari eyi lawọn obi wọn fi mu wọn lọ si ilbudo atunwaṣe yii, wọn ni Ọlọrun ti jẹ ki aye awọn yi pada ṣugbọn bi ẹni to la ina kọja ni.

Ọrọ awọn ọlọpa fihan pe ifẹ inu awọn mii tabi obi wọn ni lati mu lọ si ayédèrú ibudo atúnwàṣe yii ti wọn si san owo gọbọi fun alakoso ibẹ. Ọlọpaa ni awọn yoo ṣe ifọrọwanilẹnuwo lori eleyii.

Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Kayode Egbetokun ni agbajọwọ ikọ to ṣawari ile yii pẹlu agbekalẹ iṣẹ ọpọlọ lo mu iṣẹ naa yọri si rere ati pe awọn yoo tubọ tẹra mọ iru igbesẹ yii lati tu aṣiri awọn ibudo mii bii ti eleyi kaakiri ipinlẹ naa.

Bakan naa wọn ni awọn yoo ṣe ohun to tọ lati da awọn ti wọn ri itusilẹ yii pada sọdọ awọn mọlẹbi wọn lalafia.

Ẹwẹ, baba kan ẹni ọdun marundinlọgọrin to jẹ alakoso ibudo yii, Abdulraheem Owotutu ni oun ko fipa mu ẹnikẹni ninu awọn to wa ni ibudo yii.

Abdulraheem ti ko lee foju rẹ riran ni funra awọn obi wọn lo mu wọn wa ki wọn ba wọn mojuto ayipada iwa wọn ti wọn si ti yipada lootọ koda atawọn ti wọn mu wa ni were tara wọn ti da bayii.

Ọmọ ilu Ila ni ipinlẹ Osun ni Abdulraheem to ni oun ti wa ninu iṣẹ yii lati ọdun 1977.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Oríṣun àwòrán, Yinka Alaya/Facebook