Lagos Rape: Ẹnikẹ́ni tó bá á ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọmọ kékeré jẹ́ alárùn ọpọlọ- Onímọ̀

Adegboyega Adenekan

Oríṣun àwòrán, Facebook/women of rubies

Àkọlé àwòrán,

Iwaadi fi han pe okunrin naab jẹbi ẹsun fifi ipa ba ọmọ ọdun meji lopọ

Ẹnikẹni to ba n ni ibalopọ pẹlu ọmọ kekere jẹ alarun ọpọlọ to nilo ayẹwo.

Onimọ nipa ihuwasi eeyan, Rhoda Ikumawoyi lo sọ ọrọ naa fun BBC Yoruba ninu ifẹrọwerọ.

Ifọrọwerọ naa waye lataari bi ile ẹjọ kan nilu Eko ṣe ran ẹni ọdun mọkandinlaadọrun un to fi ipa ba ọmọ ọdun meji lopọ lẹwọn.

Okunrin ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Adegboyega Adenekan, lo ri ẹwọn ọgọta ọdun he, lẹyin ti iwadii fihan pe o jẹbi ẹsun fifi ipa ba ọmọ naa lopọ.

Onimọ nipa ihuwasi eeyan naa, Omowe Rhoda sọ fun BBC pe, ẹnikẹni to n hu iru iwa bayii ni aisan ọpọlọ to n fa ohun ti awọn kan n wọn pe ni "Pedophilia."

Omowe Rhoda ni yatọ si pe ki ijọba ran irufẹ eeyan bẹẹ lẹwọn, iru ẹni bẹẹ tun nilo ayẹwo ọpọlọ.

Rhoda ṣalaye pe ọmọ ti wón ba fi ipa balo ni kekere naa nilo iranlọwọ awọn dokita to ni imọ nipa ihuwasi eniyann ati ọpọlọ.

Àkọlé fídíò,

EkitiRapeCastration: ìgbésẹ̀ míì lè dẹ́kun ìwà ìfipábánilòpọ̀

O tẹsiwaju pe fifi ipa ba ọmọde lopọ lee ṣe ijamba nla fun aye wọn, bii ki iru ọmọ bẹ le jẹ ẹni ti yoo fẹran ibalopọ pupọ ju lọjọ iwaju.

Àkọlé fídíò,

Òwe: Kí ni ìtumọ̀ òwe ikú tó ń pa ojúgbà ẹni?

Rhoda ni: o tun lee ni ibẹru okunrin lọkan ni igbakugba to ba n ranti iṣẹlẹ ọhun.

Onimọ nipa ihuwasi eeyan naa wa rọ awọn obi lati tọju awọn ọmọ wọn obinrin daradara, ki wọn ma baa ṣagbako awọn okunrin ti arun "Pedophilia" yii n ba finra.

O ni ki gbogbo obi ati alagbatọ maa mojuto awọn ọmọ wọn, ki wọn ma jé ki wọn rin irin oru ati ki wọn ma lọ si ibi toju ko ni le to wọn.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde