Farida Saminu b'ómi lọ ṣáájú ìgbéyàwó wa - Ibrahim Abubakar

Farida
Àkọlé àwòrán,

"Nígbà ti ilẹ̀ mọ a gbọ́ ìròyìn pé wọ́n ri ẹnikan tí wọ́n ko mọ bóya o wà lára àwọn ti wọ́n ń wá tabi ibòmíràn ni o ti sàn wá.

Àwọn olùgbé Rigasa ní ìpínlẹ̀ Kaduna bọ sinu ìpàyinkeke lẹ́yìn ti wọ́n pàdánu géndé mẹ́rin àti ọmọbinrin tí ìgbéyàwó rẹ̀ ku ọjọ́ mẹ́rin péré.

Àrá ló sàn lásìkò ti wọ́n ń rin ìrìn àjò to si ba ọkọ ti wọn wà nínú rẹ̀ jẹ́ lálẹ́ ọjọ àìkú.

O tílẹ̀ ti de àdúgbò rẹ̀ nìgbà ti ìsẹ̀lẹ̀ náà fi ṣẹ̀ ti wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ si ni wá a titi ṣùgbọ́n ti wọn ko ri i títí ti o fi di alẹ́ ọjọ ajé.

Mubarak Abubakar ṣàlàyé fún BBC pé àwọn ń wá a láì ṣe aṣeyọri, titi to fi de ìlú keji ṣùgbọ́n ko si àṣeyọri kankan.

Àkọlé fídíò,

Isheri Flood: Àwọn olùgbé Isheri ń sanwó fún ọkọ̀ ojú omi láti rìn ní àdúgbò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ìyàwó mí ku ọjọ́ mẹ́rin ní ìyàwó mi b'ómi lọ

Gbogbo ènìyàn ni wọ́n ti sọ fún to fi mọ àwọn obí rẹ̀, gbogbo ìgbìyànju rẹ̀, lórí ọ̀rọ̀ isẹ́ àti ọ̀na àtijẹ náà ni, "ṣùgbọ́n ìbẹ̀ru bojo mú mi lẹ́yìn ti mọ gbọ́ nipa ìṣẹ̀lẹ̀ náà" 'mí o lè jẹun', mo di oju mi pe kíni ǹkan to ṣẹlẹ̀ gan. Eyi ni iya Farida sọ.

"Nígbà ti ilẹ̀ mọ a gbọ́ ìròyìn pé wọ́n ri ẹnikan tí wọ́n ko mọ bóya o wà lára àwọn ti wọ́n ń wá tabi ibòmíràn ni o ti ṣàn wá lórí ómi.

"Farida ṣe o ti ku ni àbi o ti ba omi lọ? baba mi ti mọ ǹkan to ṣẹlẹ̀. o ni to ba jẹ pe Farida kú, a jẹ pe àmúwá ọlọrun. To ba sì wà láàyè ọlọrun yóò fi ibi to wà hàn wá.

Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé ọjọ kẹ́wà oṣù kẹ̀wàá to kọja ni ìṣẹ̀lẹ̀ abanilọ́kàn jẹ́ yìí ṣẹlẹ̀, síbẹ̀ kò si òjò mọ ni àwọn ìpínlẹ̀ Árèwá Nàìjíríà.

Àkọlé fídíò,

'Èèyàn mi mẹ́ta ló wà nínú ọkọ̀ ojú omi tó dà nù!'