Edo Kidnap: Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí wọ́n jí obìrin kan, ajínigbé tún jí adájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Awọn gende agbebọn.

Oríṣun àwòrán, @NigerianPolice

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ajínigbé

Awọn agbebọn kan ti wọn fura si pe ajinigbe ni wọn ti gbe adajọ kan, Chioma Nwosu-Iheme ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ẹka ti ilu Benin.

Iroyin sọ pe awọn agbebọn kan naa tun pa ọlọpaa to n ṣọ ọ ki wọn to gbe adajọ lọ sibi aimọ.

Adajọ Nkechi jẹ alaga igbimọ ẹlẹni mẹta ti wọn gbe kalẹ lori awọn ipẹjọ to n suyọ latari idibo ile igbimọ aṣofin agba ati ti ipinlẹ ni ipinlẹ Edo.

Àkọlé fídíò,

Ijinigbe: BBC ṣe ìwádìí bí ikọ̀ IRT ṣe ń gbéjà ko awọn ajinigbe lójú

Eniyan kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni oun wa ninu ọkọ oun nigba ti awọn ajinigbe ṣiṣẹ laabi ọhun lopopona Benin si Agbor lẹba ile ijọsin Christ Chosen.

Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Edo, ọgbẹni Danmallam Mohammed to ni bẹẹ ni ọrọ naa ri sọ pe gbogbo igbiyanju lawọn n ṣe lati gba adajọ agba naa la.

Ọga ọlọpaa na ni ṣe ni awọn ajinigbe ọhun da adajọ ati ọlọpaa rẹ lọna loju popo ti wọn si ṣina ibọn bolẹ.

Loju ẹsẹ ni ọlọpaa naa gbẹmi mi gẹgẹ bi a ṣe gbọ ti wọn si ti n gbiyanju lati kan awn mọlbi rẹ lara.

Lọwọlọwọ aworan rẹ ti awọn eeyan ni ti igba ti o ku gbalaja loju popo ni ti n tan kalẹ lori ayelujara.

The police chief said the abductors ambushed the judge and her police orderly on the highway and opened fire. The officer died on the spot and attempts were being made to contact his loved ones.

A picture allegedly of the slain officer laying lifeless on the highway had made social media rounds on Wednesday afternoon.

Àkọlé fídíò,

Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

Iṣẹlẹ ijinigbe yii waye lẹyin ọsẹ ranpẹ ti wọn ṣẹṣẹ ji adari agba ile iwosan akọṣẹmọṣẹ Irua, Ọjọgbọ́n Sylvanus Okogbeini, iyawo adari ẹka kan ni ileeṣẹ Reluwee, arabinrin Francisca Okhiria ati adari ile iwe girama kan toun fara pa.

Ṣugbọn iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe ati adari ile iwosan akọṣẹmọṣẹ ati iyawo adari ẹka kan ni ileeṣẹ Reluwee ni wọn ti tu silẹ.