Soyombo yẹ fún àyẹ́sí gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagì oníròyìn - Aregbesola

Aworan Minisita Rauf Aregbesola ati akọroyin Fisayo Soyombo

Oríṣun àwòrán, @raufaregbesola, fisayosoyombo

Minisita to n ri si ọrọ abẹnu, Rauf Aregbesola ti gboriyin fun oniroyin atọpinpin ọmọ Naijiria kan to n gba abẹle ko iroyin jọ titi to fi tu aṣiri iwa ibajẹ to n waye nileeṣẹ ọgba ẹwọn ni Naijiria.

Fisayo Soyombo lorukọ akọroyin yii n jẹ, o ti figba kan jẹ alamojuto iroyin fun ile iṣẹ iroyin The Cable to si ti ṣe iroyin to tu aṣiri gbigba owo abẹtẹlẹ ninu iṣẹ awọn onimọ ofin nipa iwa ọdaran.

Odidi ọsẹ meji ni akọroyin yii lo latimọle tori ati tọpinpin iwa ibajẹ nile iṣẹ naa. Ọjọ marun un lagọ ọlọpaa ati ọjọ mẹjọ lọgba ẹwọn Ikoyi nilu Eko ni o lo.

Minisita gboriyin fun iṣẹ arakunrin yii ati ileeṣẹ iroyin The Cable fun iṣẹ takuntakun ti Soyombo dawọle pẹlu ajọṣepọ ilbi iṣẹ rẹ.

"Bi ẹ ba n dupẹ lọwọ ajọ bii EU atawọn ajọ agbaye to ku, itanjẹ gbaa ni yoo jẹ bi a ko ba mọ riri iṣẹ takuntakun ti Soyombo ṣe". Aregbesola ni

Àkọlé fídíò,

Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

"A n mọ riri a si n ṣe ayẹsi akọroyin atọpinpin yii ni ibamu pẹlu ilana ẹkọ fun iṣẹ takuntakun rẹ... Paapaa mo tun gbudọ gboriyin fun ileeṣẹ to ṣe eyi nitori mo rii pe iṣẹ agbajọwọ ni".

Aregbesola tun bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe maa n ṣe awn ẹlẹwọn lọna aitọ eyi to ni o maa n dina mọ ayipada wọn gẹgẹ bi araalu.

O ni ọna kan ti ẹ lee fi ri eeyan to jade lẹwọn tori rẹ si ti pe ni lati kọ ẹni bẹẹ lẹkọ, "ohun taa si n ṣe nibi niyii".

Àkọlé fídíò,

Àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé òbí wọn máa ń padà wá sáyé