Osu mẹ́ta si mẹ́rin ni à fi n so wọ́n mọ́lẹ̀ fun ìwòsàn -Pasitọ Ojo

Pasito Ojo

Oríṣun àwòrán, @PUNCH

Àkọlé àwòrán,

Àṣírí pásìtọ̀ tó ń fí sọ́ọ̀si ṣe ọ̀gbà wèrè tú

Olùsọ́àgùtàn Joseph Ojo, tí ọwọ ṣìkún ọlọpàá ti mú fún lílo ilé ìjọsìn rẹ̀ àgbègbè Ijegun ni ìpínlẹ Eko gẹ́gẹ́ bi ẹwọn fún àwọn alárun ọpọlọ àti àwọn ti wọn ni ààrun kan tàbi òmíràn.

Ìròyin sọ pé ọlọpàá mú Ojo lẹ́yìn ti ẹka ọlọpàá Isheri-Osun tú àwọn ènìyàn mẹ́ẹ̀dógún sílẹ̀ nínú ilé ìjọsìn rẹ̀ ní ọjọrú lẹ́yìn ti àwọn àjọ kan ti kìí ṣe ti ìjọba tá ilé iṣẹ́ ọlọpàá lólobó.

Abẹwò sí ìjọ náà ní ọjọbọ ni àwọn ọlọpàá ba àwọn ènìyàn ti wọ́n so mọ́lẹ̀ bi ẹran àmúso tí àwọn míràn sì ń sọrọ̀ tri kò jọrawọn.

Ojo sàlàyé fún àwọn akọròyìn pé òun so àwọn ènìyàn náà mọ́lẹ nitórí ipò ti wọn wà, àti pé ọ̀pọ̀ wọ́n ni òbí wọ́n mú wá fún ìtúsílẹ̀ àti ìwòsàn.

O ní " a so àwọn ènìyàn yìí mọlẹ̀ nítori ipò ti wọ́n wà, ti a ò bá so wọ́n mọ́lẹ̀ wọn a sálọ, wọ́n ti ko mi sí wàhálà sẹ́yìn, nítori náà ni mo ṣe so wọ́n ti ara wọ́n bá ti ya ni a máa n tú wọ́n sílẹ̀."

Àkọlé fídíò,

Helgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil

Pasitọ Ojo ni: "Ibí kìí ṣe ilé ìwòsàn ti wọ́n ti n wo àrùn ọpọlọ sùgbọ́n ọ̀pọ̀ wọ́n ni wọ́n ti kọ́kọ́ gbe lọ si ilé iwosan ti wọ́n ti n wo wèrè ki wọ́n tó gbe wọ́n wá síbi."

"Bí osù mẹ́ta si mẹ́rin ni a maa fi n so wọ́n mọ́lẹ̀, àwọn ẹbi wọ́n si ni yoo máa fún wọn lóunjẹ, àwọn ẹbi àwọn mírànn máa ń wá lójoojúmọ, àwọn míràn ọsẹ̀-ọ̀sẹ̀, nígbà ti àwọn míràn ń gbe pẹ̀lú ẹbí wọ́n nínú ìjọ"

Ọkan nínú àwọnn ti wọ́n ti so mọ́lẹ̀ fún oṣù mẹ́jọ nibẹ, Adewale Adetona sàlàyé pé wọ́n ji òun gbé ni, àwọ́n ẹbi oun si gbe oun wá si ilé ìjọsin náà, o ni kò dùn mọ oun láti maa gbe sọ́ọ̀sì.

Àkọlé fídíò,

Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

Ẹ̀wẹ̀ ìyá Adewale, Monsurat sàlàyé pe fúnra oun ni oun gbé ọmọ náà wa si ilé ìjọsin ọhun fún àdura, nitori o maa n doju ti ẹbi láàrin igboro.

Ijọ Blessings of Goodness Healing Church ni ijegun Isheri yii ni awọn ọlọpaa ti tu awọn eniyan naa silẹ gẹgẹ bi Bala Elkana to jẹ agbẹnusọ awọn ọlọpaa ṣe ṣalaye.

Àkọlé fídíò,

Àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé òbí wọn máa ń padà wá sáyé