Zlatan sọ ìtumọ̀ òrin rẹ̀ tó gbòde kan

Olorin Zlatan Image copyright Zlatan/Facebook

O ti ṣe diẹ ti gbajugbaja ọdọ olorin ọmọ Naijiria Zlatan Ibile ti fi ikede sita pe oun yoo gbe orin tuntun kan jade lonii ọjọ kinni oṣu kọkanla ọdun 2019.

O pe akọle awo orin naa ti gba ẹnu awọn eeyan kan lori ayelujara ni "Zanku" to si funra rẹ sọ loju opo Twitter rẹ pe itumọ bi ẹ ba lo Zanku laarin ọrọ ni pe "Ma pa mi".

Zlatan ṣe ikede yii loju opo Instagram rẹ lati ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹwa ọdun 2019 to si mẹnu ba ohun to ti la kọja laye ninu ọrọ rẹ to fi sita.

O ni adapọ irora, ẹrin, ijakulẹ, alekun, ibinujẹ, alafia ati bẹẹ lọ loun ti ri laye. "Ṣugbọn ninu ohun gbogbo naa, Ọlọrun jẹ olotitọ, lai si Ọlọrun i ba ma si ẹni ti a n pe ni Zlatan Ibilẹ".

"Nitori naa, inu mi dun lati kede gbogbo oniruuru orin to wa ninu awo orin mi tuntun, ZANKU".

Lara awọn ti wọn jọ kọwọ kọ orin naa ni Davido, Burna Boy, Tiwa Savage, Patoranking ati Barry Jhay.

Image copyright zlatan_ibile

Wo lara oriṣiriṣi fọnran ijo Zanku tawọn eeyan n fi sita

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHelgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil