Lagos Building Collapse: Àwọn agbáṣẹ́se bá BBC sọ̀rọ̀

Ile alaja to wo lulẹ

Wọn ti yọ awọn to wa labẹ ile to wo ni ikoyi ni ikede tuntun ti ajọ LASEMa fi sita.

Adari ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ eko, Omowe Femi Oke- Osanyintolu ti fidiẹ mulẹ fun BBC pe wọn ti gbe awọn mẹrin to ku lọ sile iwosan fun itọju to peye.

O ni wọn ti gbe oku ẹnikan to ku sinu iṣẹlẹ naa lọ sile igbokupamọ si.

Bakan naa lo ṣalaye pe awọn ohun eelo ti wọn fi kọ ile naa ko kunju oṣuwọn to lo ṣokunfa ile naa to da wo ni Ikoyi ni ipinlẹ Eko ṣugbọn iṣẹ iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ ohun to ṣẹlẹ gangan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLagos King: Mátikú ọba tó lo lo ọdun mẹta lórí oyé latari rogbodiyan Eko

Kini o ti ṣẹlẹ tẹlẹ?

"Èèyàn kan ṣi ha s'ábẹ́ ilé tó wó n'Ikoyi, Àjọ LASEMA ẹ bá wa wá ǹkan ṣe o!" ni ariwo to gba ẹnu awọn eniyan agbegbe Ikoyi kan lẹyin ti ile kan wo nibẹ.

Akọ̀ròyìn BBC Yorùbá tó wà níbẹ̀ jábọ̀ pé àjọ LASEMA ti ní kí àwọn èèyàn tó wà lágbègbè ṣe pẹ̀lẹ́.

Lọsan gangan ni ile gogoro naa wo lulẹ lonii ọjọ kinni oṣu kọkanla lagbegbe Glover Court, Ikoyi l'Eko.

Aja meji ni ile ọ̀hun ti wọn ṣẹṣẹ n kọ lọwọ gẹgẹ bi ikọ BBC Yoruba to wa nibi iṣẹlẹ naa ṣe fabọ jẹni.

Eniyan mẹrin to fara pa nibi iṣẹlẹ yii ni wọn ti gbe lọ si ile iwosan fun itọju gẹgẹ bi ajọ LASEMA ṣe sọ ọ, "bẹẹ si ni a n ṣe akitiyan lati yọ awọn mii to ba ṣeeṣe ki wọn wa labẹ ile wiwo naa.

Lara awọn agbaṣẹṣe tó n kọ ile naa Nurudeen ṣalaye fun BBC Yoruba pe oṣiṣẹ kan pe, Yọmi ọmọ kekere ṣi wa ninu ile naa.

O ni Yomi n sun lọwọ labẹ ile naa nigba to wo lulẹ to si ni wọn ko tii ri i yọ jade.

Nurudeen sọ pe , lati ibẹrẹ oṣu to kọja ni oun ati ẹnikeji oun ti n wa si ibi iṣẹ yii ti wọn ko si tii san owo fun wọn, to wa n rọ awọn ajọ LASEMA lati tete gbe ọmọ naa jade.

Ẹwẹ, iroyin yii ti de eti igbọ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA ti wọn si ti kan si ikọ amuṣẹya wọn ki wọn tara ṣaṣa lọ sibi iṣẹlẹ naa.

Bakan naa wọn ti rọ awọn ara ilu Eko to wa lagbegbe na lati wa ni pẹlẹ ki wọn jẹ ki ikọ amuṣẹya ṣe iṣẹ wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHelgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ to gbaṣ ṣe nibẹ s fun BBC ninu iwanilẹnuwo pe "àwa la dóòlà àwọn mẹ́rin tó wà nílé ìwòsàn kìí ṣe àjọ LASEMA".

O ni awọn ko ri ọkọ katakata ti wọn ni awọn fẹ lọ gbe wa lati bii wakati mẹta bayii bẹẹ si ni o sọ pe "o ku èèyàn kan lábẹ ilé o, kí wọ́n bá wa wá a jáde".

Ajọ LASEMA ni iṣ ṣi n lọ lọwọ lati rii pe ohun gbogbo pada bọ pada si alafia.

Arakunrin kan ti o tun ba ikọ BBC sọrọ ti o n jẹ Emmanuel ṣalaye pe ni kete ti ogiri ile naa ya lulẹ ni wọn ti doola ẹmi ẹnikan to ha sinu iṣẹlẹ naa ti orukọ rẹ n jẹ Everest.

Ni bayii, awọn ajọ ti n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Ipinlẹ Eko ti wa lojuko naa lati doola ẹmi Yọmi ti ile naa wo le lori.

Amoju ẹrọ onimọ nipa ile kikọ kan nibẹ Gbolahan Ishau to tun jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ni lootọ ilẹ ti ṣu ṣugbn wọn yoo ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ.

Awọn oniroyin beere pe ṣe lootọ ni pe ayederu ni awọn nkan ti wọn fi n kọ ile naa. Ishau sọ pe, ile iṣẹ to n ri si iṣẹlẹ yii yoo ṣe iṣẹ wọn oun naa yoo si mu abọ pada lọ sile aṣofin.