Mátikú; Oba ìlú Eko tó forí oyè sílẹ̀ lọ́dún 1931 kí àlàáfíà lè jọba
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lagos King: Mátikú ọba tó lo lo ọdun mẹta lórí oyé latari rogbodiyan Eko

Ki itan awọn akọni atijọ ma le parun ni wọn ṣe ṣere Matiku lori itage.

Bi ọmọ ko ba ba itan, o di dandan ko ba arọba ni ọrọ ohun to ṣẹlẹ ni ilu Eko adele, aromisa lẹgbẹlẹgbẹ lọdun 1928 si ọdun 1931.

Oba meji lo jẹ ti wahala ati laasigbo si bẹrẹ ki Oba Matiku to fori oye sile ki alaafia le jọba ni ipinlẹ Eko to ṣi wa ni ilu labẹ oyinbo ajẹlẹ nigba naa.

Omowe Bisoye Eleṣin to jẹ olukọni ni fasiti ijọba apapọ nipinlẹ Eko lo kọ iwe naa si ere oniṣe lori itage.

Oba Sanusi Olusi ni wọn tumo si Matiku ni eyi to jẹ olu ẹda itan fun iwuri fawọn olori ati oloṣelu asiko yii pe ko si nkan ti eeyan ko le ṣe fun alaafia awọn ti o n dari.