Mi ó lè na apá mi àmọ́ mo lè lo ọpọlọ mi fí kọrin-Ayeyi
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Osteogenesis, aisan níní egungun tó rọ̀ ló ń ba Efia fínra

Ọdọmọde to n ba aisan egungun ti kò ní ìmí fínra

Efia Ayeyi lorukọ ọmọ ọdun mẹjọ yii to ti pinnu lati fi ayọ gbe igbe aye rẹ lainiifiṣe iṣoro to ni.

Aisan Osteogenesis Imperfecta to nii ṣe pẹlu egungun ni o n ba ọdọmọde yii finra.

Egungun rẹ rọ gan an ni, o le kan nigbakigba nitori pe egungun naa ko ni ìmí ninu.

Efia Ayeyi ṣalaye pe oun fẹran lati maa jo, lati maa kọrin, lati maa ṣere, lati maa kawe ṣugbọn inira maa n wa fun un ni ọpọ igba.

Ọpọ igba ni egungun Ayeyi maa n deede rọ tabi ko kan ni eyi to n jẹ ki akitiyan iya rẹ pọ sii fun itọju rẹ.

Ayeyi ni pẹlu iranlọwọ Olorun,omi mimu lasiko ati ere idaraya, iyatọ ti n ba oun.