BBC Pidgin Essay Competition: Ikechukwu Wilson ló fi 500 dollars ṣe ara rindin

Ikechukwu Wilson winner of BBC Pidgin Essay Competition

Ikechukwu Wilson Nweke ni ẹni to jawe olubori ninu idije arokọ ti ile iṣẹ BBC Pidgin fun ọdun 2019.

Ikechukwu to jẹ akẹẹkọ 200 Level ni fasiti ile iwe giga ti ilu Benin lorilẹede Naijiria, ni bi ti o ti n kẹkọ imọ International Studies and Diplomacy.

Nibi ayẹyẹ arokọ naa ni ilu Eko ni BBC Pidgin ni wọn ti kede re gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori lẹyin to ka arokọ naa si ẹti awọn to wa nibi ayẹyẹ naa.

Akọle arokọ ti Ikechukwu kọ to fi bori lo sọ wi pe awọn obinrin ti ṣetan lati ṣe ijọba lorilẹ-ede Naijiria.

Ikechukwu fikun wi pe oun ko arokọ naa lati le fihan wi pe o daara lati ṣe deede laarin akọ ati abo.

Arakunrin to jawe olubori naa fi idunnu rẹ han pe oun jawe olubori, to si ni wi pe oun ko lero rẹ, nitori oun ṣe aisan lasiko ti oun kọ arokọ naa.

Igba keji re e ti BBC News Pidgin se agbekalẹ arokọ ọlọdọọdun naa, eleyii ti wọn si pinnu lati ma a ṣe lọdọọdun.

Wo awọn Adajọ ti wọn máàki arokọ naa:

1.Omowe Miriam Ayafor

Omowe Ayafor gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ni fasiti Yaoundè, o gba oye ipele keji MA ni fasiti Leeds ko to wa gba oye ọmọwe ni fasiti Ulster.

Ogbontarigi obinrin onkọwe yii n ṣiṣẹ olukọ ede oyinbo ati imọ ẹda ede lawujọ ni fasiti Yaounde 1, ni orilẹ-edeCameroon.

2.Ojọgbọn Offiong Ani Offiong

Ojọgbọn Offiong Ani Offiong, jẹ ọjọgbọn ninu imọ ẹda ede ati ibaraẹnisọrọ ni fasiti Calabar ni orilẹ-ede Naijiria.

Ojọgbọn Offiong ni adari ẹka Faculty of Arts lọwọlọwọ ni fasiti Calabar.

3.Ọjọgbọn Francis Egbokhare

Ọjọgbọn Francis Egbokhare jẹ ogbontarigi onkọwe, o jẹ akọṣẹmọṣẹ ninu imọ ẹda ede ni Naijiria paapaa Fonẹtiiki ati fonolọji ati agba ọjẹ Fellow ni Nigeria Academy of Letters.

Fasiti akọkọ ni Naijiria to wa ni Ibadan nipinlẹ Oyo ni guusu Naijiria lo ti n ṣiṣẹ olukọ agba. O ti ṣe adari ẹka awọn akẹkọọ ọna jinjin fun ọpọlọpọ ọdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC gbalejo ọmọ Ibadan

4.Ọgbẹni Adejuwon Soyinka

Adejuwon Soyinka, jẹ ọkan lara awọn ti alami ẹyẹ Emmy n wo iṣẹ wọn wo fun ami ẹyẹ ọdun 2019.

Juwọn Soyinka ni adari ẹka ede Pidgin ni ileeṣẹ BBC, O ni imọ ijinlẹ ipele keji ni imọ ofin awọn orilẹ-ede ati ajọṣepọ wọn.

O ti ṣiṣẹ iroyin ni ipele oloṣelu ati ti aladani fun ogun ọdun .

5.Ọjọgbọn Kofi Yakpo

Kofi Yakpo jẹ ọjọgbọn ninu imọ ẹda ede ni fasiti Hong Kong.

O jẹ olubadamọran ninu oṣelu pẹlu alaṣẹ German ni Berlin. O tun jẹ ajajangbara fawọn ọmọ ilẹ Adulawọ.

O gba oye ọmọwe ninu imọ ẹda ede ni fasiti Radboud ni Netherlands.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIko BBC Yoruba tuntun

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí