Azman Airline: Ọkọ̀ òfúrufú gbiná nítorí obìnrin tó ń fa Shisha!

Azman Airline Image copyright OTHERS
Àkọlé àwòrán Ẹni ti ọ̀rọ̀ náà sojú rẹ̀ ní ọmọbinrin kan ló mú fa Shisha, tí ó gbàgbé pa iná rẹ̀, kí ó tó wo inú ọkọ̀ ofùrufú.

Oko ofurufu Azman to n lọ lati Eko si Abuja ni o deede yọ eefin lana.

Boeing 737 naa ni iroyin ni pe o nilati pada wa si Eko lẹyin iṣẹju mẹwaa to gbera.

Ọkọ baalu Azman naa lo bẹrẹ si ni ṣe efin lẹyin ti obnrin to wọ ọkọ ofurufu naa fa shisha ti ko si pa ina rẹ daadaa ko to wọ ọkọ ofurufu.

Arakunrin to wa ninu ọkọ baalu to n lọ si Abuja lati ilu Eko, Ogbẹni Valentine Iwenwanne lo sọ bẹẹ fun BBC lẹyin ti o fi ọrọ naa lede si oju opo Twitter rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsteogenesis, aisan níní egungun tó rọ̀ ló ń ba Efia fínra

Arakunrin Valentine salaye fun BBC pe obinrin naa n fa shisha naa ki o to wọ ọkọ baalu, amọ o gbagbe lati pa ina rẹ daadaa ki o to gbe e wo inu ọkọ baalu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'

Ninu ọkọ baalu ni ẹni ti wọn jọ joko ti sọ fun un pe eefin n yọ ninu baagi rẹ, ti o si salọ si inu yara igbọnsẹ, ki eefin naa to wa gbina.

Awọn osisẹ baalu naa tiraka titi wọn fi pa ina naa lẹyin ti aago ijamba ina ‘alarm’ bẹrẹ si ni pariwo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPrepaid Meter: èrò àwọn èèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí 'sisan owó iná ní Nàìjíríà

Bawo ni Shisha e kọja ayẹwo ni papakọ ọkọ ofurufu Eko?

Lẹyin naa ni ọkọ naa pada si papakọ Eko, ti awọn ero ọkọ baalu naa si sọ wi pe awọn koju ọpọlọpọ idaamu lati wọ ọkọ miran.

Kinni alaṣẹ Azman àti FAAN ati NCAA n sọ?

Awọn alasẹ ọkọ baalu Azman fi ontẹ lu u pe lootọ ni isẹlẹ naa waye, ati wi pe Ajọ to n risi irinkerindo ọkọ ofurufu, NCAA ti fi panpẹ ọba mu obinrin naa fun iwadii kikun.

Bakan naa ni ẹka isejọba to n risi ọrọ ofurufu, FAAN fikun un wi pe iwadii n lọ lọwọ lori isẹlẹ naa, amọ ko seese ki eniyan gbe Shisha kọja ni awọn ibi ayẹwo igbalode to wa ni papa ofurufu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBalogun market fire: Olubadamọran gomina sọrọ lori ina náà

Nigba ti BBC n fidi ọrọ naa mulẹ fun wọn lati fihan pe obinrin yii gbe ṣhiṣha wọle ni wọn fi nọmba ọga miran silẹ lati ba sọrọ ṣugbọn gbogbo igbiyanju wa ja si pabo lati ba ẹni naa sọrọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'