Osun Police: Ẹnikẹ́ni tó bá tún fa wàhálà lẹ́sẹ̀ yóò rí pípọ́n ojú ìjọba

Ilu Ile Ifẹ Image copyright Others

Jinijini dabo awọn eniyan agbegbe Sabo nilu Ife ni Ipinlẹ Osun laarọ ọjọ Ẹti nigba ti eeyan meji jalaisi, ti ọkan ninu wọn jẹ Yoruba nigba ti ekeji si jẹ Hausa.

Inu hilahilo ni awọn eniyan agbegbe naa wa nigba ti wọn ba oku awọn ọkunrin meji ọhun nilẹ ni Abule Aruwa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Alukoro fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ọsun, Folasade Odoro, to fidi isẹlẹ naa mulẹ, salaye pe alaafia ti n pada bọ si agbegbe ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ileesẹ ọlọpa Ọsun ti taari ọgọọrọ ọlọpa sibẹ lati dena ki ọwọja laasigbo yii tankalẹ laarin ẹya Hausa ati Yoruba, ti ohun gbogbo si ti pada bọ sipo.

Image copyright Others

Odoro fikun pe Kọmiṣana Ọlọpaa Ipinlẹ Ọsun ti paṣe pe ki ẹnikẹni maṣe fa eṣu lẹsẹ, ẹnikẹni to ba si kọti ikun si asẹ yii, yoo ri pipọn oju Ijọba.

O ni awọn eeyan agbegbe naa ti n ba eto ọrọ aje wọn lọ laisi wahala, ti gbogbo ibẹ si ti tuba tusẹ.

A gbọ pe ija kan lo bẹ silẹ ni abule Aruwa yii, eyi to mu ẹmi eniyan meji ọhun lọ, lo waye laarin awọn awakusa to jẹ alagbase, ọna lati dẹkun igbiyanju lati gbẹsan awọn eeyan to ku naa, lo mu kileesẹ ọlọpa ya lọ si abule naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ija ajakuakata ni Sabo Ife

Iro ibọn n dun lakọ lakọ lagbegbe naa, to si mu ki ọpọ eeyan maa sa asala fun ẹmi wọn, ti ọrọ aje agbegbe naa si mẹhẹ.

Ẹnikan ti ọrọ ọhun ṣoju rẹ ṣalaye pe, awọn eleto aabo ti wọn ran wa lati pese aabo lo n yinbọn lakọlakọ.