Lagos Fire: Ọpọ dúkìá olówó iyebíye tún bá iná lọ

ina tojo ni Eko Image copyright facebook
Àkọlé àwòrán Ibi ina okobaba

Ijamba ina miran tun ti ṣẹyọ ni ilu Eko ti o si jo ọpọ ile ati dukia ni agbegbe Okobaba ninu ọja pako to wa nibẹ.

Ọṣẹ ti ina naa ṣe ti mu ile marun un miran, ti o si jo wọn raurau.

Ileesẹ panapana ati ajọ LASEMA tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Eko ni, awọn ti n sa gbogbo ipa lati pa ina naa.

Nigba to n ba ile iṣẹ BBC Yoruba sọrọ, Oludari agba fajọ Lasema, Femi Osanyintolu ṣalaye pe, gbogbo agbara ni ile iṣẹ naa n sa lati daabo bo dukia ati awọn eniyan.

O ṣalaye siwaju pe, ko si ẹmi to sọnu sinu ijamba naa, ti ko si sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa ina naa ṣẹyọ lojiji.

Image copyright facebook
Àkọlé àwòrán Awon eniyan n pa ina naa

Oludari ajọ Lasema tun ni ko si ẹni to le sọ pato iye dukia to ba ina naa lọ, titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Ti a ko ba gbagbe lẹnu aipẹ yii ni ina ṣẹyọ ni inu ọja Balogun ti o wa ni ilu Eko bakan naa, ti ẹmi ati dukia si ba iṣẹlẹ naa lọ.

Image copyright facebook
Àkọlé àwòrán Awon ti oro ina naa taba