Lagos 2020 Budget: Sanwo-Olu ní pẹ̀lú àbá ìṣúná 2020, ẹ̀kún omi yóò dìtàn l‘Eko

Sanwo-Olu n gbe aba isuna 20020 kalẹ siwaju awọn asofin Eko Image copyright Lagos state Government

Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti fi aba eto iṣuna Ipinlẹ naa fọdun 2020 ranṣẹ si ile Igbimọ Aṣofin.

Apapọ owo to wa ninu aba isuna naa lo jẹ Triliọnu kan ati biliọnu kan naira.

Nigba to n gbe aba naa kalẹ, gomina Eko ni wọn yoo ri owo lati gbọ bukata eto isuna ọhun lati ara owo ti ijọba n pa wọle labẹnu, to jẹ triliọnu kan o le diẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iṣuna naa lo fi ida mẹrinlelọgbọn ju ti ọdun 2019 lọ. Akanṣe iṣẹ nla nla yoo gba owo ti o to biliọnu lọna okoolelẹẹdẹgbẹrin ati mẹta naira (₦723.6bn) nigba ti owona atigbadegba jẹ biliọnu lọna ojilenirinwo ati ẹyọ kan naira (₦441.8bn).

Image copyright Lagos state Government

Gẹgẹ bi Gomina ti wi, o ni eyi wa fun idagbasoke ti yoo mu iderun ba tolori tẹlẹmu lawujọ, ti yoo si jẹ ki wọn ni imọlara eto idagbasoke.

Ki eyi le di mimu ṣẹ, Gomina Sanwo Olu ni Ijọba ti pese biliọnu mọkanla ole diẹ naira gẹgẹ bi owo ti yoo wa fun eto to maa nipa lori awujọ .

"Ni afikun si eyi, ati ṣe ipese ti o to biliọnu meje naira lọdun yii lati mu idagbasoke ba ile iṣe, ibudokọ, ironi lagbara awọn ọdọ ati ọja fun gbogbo oniṣẹ ọwọ."

Eyi yoo tun "se atilẹyin fun awọn oniṣowo kekeke ti o jẹ ọpakutẹlẹ fun idagbasoke ọrọ aje ati ipese iṣẹ."

Image copyright Lagos state Government

Bakan naa ni o tun lero lati pese biliọnu metadinlaadọsan -an ti o wa fun sisaan owo oṣu ti yoo si tun wa fun ọrọ to ni ṣe pẹlu oṣiṣẹ.

Eyi jẹ ida mejilelogunlara owo ti ijọba n pa wọle labẹle , ti o si wa ni ibamu ida lọna marundinlọgbọn owo oṣu iye ti ijọba n pa wọle pẹlu ilana lati san owo oṣu titun.

Eto iṣuna ti o kọja iye ti wọn na ti o le ni ẹẹtadinlọgọrun-un biliọnu ni ijọba yoo gbiyanju lati wa wọrọkọ fi ṣada fun lati ile okeere ati nilẹ yii.

O ni, gẹgẹ bi a ti mọ wi pe pipa owo wọle ni igi lẹyin ọgba eto iṣuna, ti iṣuna yii yoo faramọ awọn eka ti o pa owo wọle.

Bakan naa ni iṣuna yoo mu idagbasoke ba eto ẹkọ,eto ileraati awọn ohun idagbasoke miran.

Image copyright Lagos state Government

O ni bo tilẹ jẹ pe owo ti wọn na lori iṣe ode ati amayedẹrun jẹ biliọnu mọkanlelọgbọn ni oṣu kẹsan ọdun 2019 ni itako ilana iṣuna ọdun 2019 ti o jẹ biliọnu mejidinlọgọrin.

Ti o wa ni ijọba ni lọkan lati na aarundinlọgọfa biliọnu naira ni ọdun 2020.

Gomina naa wa ni eto ẹkọ yoo gba koriya si ti owo iṣuna rẹ yoo jẹ mejidinlaadọta biliọnu naira ti o jẹ ida ọgọta ju ti ọdun 2019 ti iyẹn jẹ ọgbọn biliọnu naira.

O wa ni ijọba yoo sowọpọ pelu ijọba ibilẹ lati mu igbedide ba eto ẹkọ alakọbẹrẹ ati lati fun awọn olukọ ni imọ kun imọ lori imọ ẹrọ.

Image copyright Lagos state Government

Lori ọrọ eto ilera , o ni ijọba ṣeto biliọnu metalelọgbọn yatọ si ti ọdun 2019 ti o jẹ biliọnu mọkanlelogun, ti o si ni pe eto ilera ẹsẹ kuku gbọdọ gberu si fun eniyan ilu.

O ni, ilu Eko jẹ ti gbogbo mutumuwa ti a gbọdọ maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn aladani lati mu eto ilera ba tẹrutọmọ.

Lori ẹkun omi yale nilu Ẹko, ijọba ti ya biliọnu mẹsan sọtọ fun eyi ni ọdun 2020 lafiwe pẹlu biliọnu mẹta naira ti ijọba pese ni ọdun 2019.

Sanwo Olu ṣalaye pe, ajọro to nipọn ni ijọba dawọle lati ẹkun idibo mẹteeta Ipinlẹ naa, lati mọ ohun ti awọn eniyan fẹ, ti awọn Aṣofin si n ṣe pẹlu eniyan wọn.