Ọkọ̀ kan tàkìtì nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé lẹ́bá afárá Third Mainland l'Èkó

Iṣẹlẹ ijamba ọkọ nilu Eko Image copyright @followlastma
Àkọlé àwòrán Ajọ LASTMA ko sọ boya ẹnikẹni ṣeṣe ninu ijamba naa

Ijamba ọkọ kan ti waye lagbegbe Olopomeji, ni abawọle afara Third Mainland to wa ni ilu Eko.

Ajọ to n risi igbekogbodo ọkọ ni ipinlẹ naa, LASTMA fi idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ loju opo Twitter rẹ.

Ajọ naa rọ awọn eeyan to n gba agbegbe ọhun lati ṣọra nitori sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ to ti n korajọ lojuko iṣẹlẹ ọhun.

Ọkọ Volkswagen to ni nọmba idanimọ SMK 46EH ti ilu Eko lo takiti, to si fi ẹyin lelẹ.

Image copyright @followlastma

Ajọ LASTMA ko sọ boya ẹnikẹni ṣeṣe ninu ijamba naa.

Image copyright @followlastma

Awọn oṣiṣẹ ajọ LASTMA ti wa nibi ti ijamba naa ti waye ti wọn si ti n ṣe iranwọ fun ti iṣẹlẹ naa ṣẹ si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIllegal Rehab Centre: A le ni ogójì tí wan n kó 'sinú ìyará kékeré kan níle Ọlọrẹ