Ẹ lọ wá bi jókó sí, Sanwo-Olu ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó - Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Image copyright @jidesanwoolu
Àkọlé àwòrán Ile ẹjọ naa ni ṣe ni olupẹjọ fi akoko ilẹ ẹjọ ọhun ṣofo, lẹyin naa lo da ẹjọ naa nu

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ipinlẹ Eko ti da ẹjọ ti ẹgbẹ Labour pe tako bi ajọ to n ri si eto idibo, INEC, ṣe kede Babajide Sanwo-Olu gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ naa nu.

Ilẹ ẹjọ ọhun ni Babajide Sanwo-Olu ni ojulowo ẹni to jawe olubori ninu idibo sipo Gomina nipinlẹ Eko.

Igbimọ ẹlẹni marun un to n gbọ ẹjọ naa sọ pe, ẹjọ ti ẹgbẹ Labour pe ko ni gbongbo.

Image copyright @jidesanwoolu

Ẹgbẹ Labour pe ẹjọ naa latari bi wọn ṣe ni, Sanwo-Olu ko pegede lati dije sipo Gomina nipinlẹ Eko, ati pe oun kọ lo jawe olubori ninu idibo sipo Gomina to waye lọjọ kẹsan an, oṣu kẹta ọdun 2019.

Adajọ Hannatu Sankey to ka idajọ awọn igbimọ naa sọ pe, Sanwo-Olu lo jawe olubori ninu idibo ọhun.

Ile ẹjọ naa ni ẹgbẹ Labour kuna lati pese ẹri, lati lee fi idi rẹ mulẹ pe Sanwo-Olu ko pegede lati dije sipo Gomina l'Eko.

O ni, ṣe ni olupẹjọ naa fi akoko ilẹ ẹjọ ọhun ṣofo, lẹyin naa lo da ẹjọ ọhun nu.

Ṣaaju ni ẹgbẹ Labour ti kọkọ lọ ile ẹjọ to n gbọ ẹsun eto idibo nipinlẹ ọhuu, ṣugbọn ile ejọ na da ẹjọ naa nu, lẹyin eyii ni o lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIllegal Rehab Centre: A le ni ogójì tí wan n kó 'sinú ìyará kékeré kan níle Ọlọrẹ