Premier League: Arsenal jẹ àjẹkún ìyà lọ́wọ́ Leicester City pẹ̀lú àmì ayò 2-0

Image copyright Getty Images

Ikọ Leicester City sun siwaju ninu idije Premier League lẹyin ti wọn fẹyin Arsenal gbolẹ pẹlu ami ayo meji si odo ninu ifẹsẹwọnsẹ loni.

Ṣaaju ninu ifẹsẹwọnsẹ naa ni ikọ naa ti gbiyanju lọpọ igba lati sọ goolu sinu awọn, koda Wilfred Ndidi sa ipa rẹ, ṣugbọn, pabo lo ja si.

Ninu abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa ni Vardy ti sọ goolu rẹ kọkanla ni saa yii sawọn ile Arsenal, lẹyin ti Harvey Barnes ati Youri Tielemans ti domi siwaju fun un.

Image copyright Getty Images

Laipẹ sii ni Maddison naa ṣe bi okunrin, ti oun naa gba bọọlu saarin ẹse Héctor Bellerin, leyi to wọle tara sinu awọn ile Arsenal.

Bi ikọ Leicester City ṣe pegede yii tumọ si pe, wọn ti tẹsiwaju si ipo keji ninu idije Premier saa yii.

Bakan naa ni ikọ Arsenal sun si ipo kẹfa ninu idije naa to n lọ lọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIllegal Rehab Centre: A le ni ogójì tí wan n kó 'sinú ìyará kékeré kan níle Ọlọrẹ