Governors vs Miyetti Allah: 'Àwa ò ṣetán láti fáwọn darandaran nílẹ̀ ní ìpínlè wa'

Fulani Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Fulani Darandaran

Awọn Gomina kan kaakakiri ẹkun Gusu ati Aarin gbungbun orilẹ-ede Naijiria ti yari pe awọn ko ṣetan lati yọnda ilẹ wọn fawọn darandaran lati tẹdo.

Awọn gomina yii ni faabada, awọn ko ni jọwọ ilẹ ni agbegbe awọn, wọn ni idunkoko ti awọn Fulani darandaran n ṣẹ labẹ akoso ẹgbẹ wọn ti a mọ si Miyatty Allah Kautal Hore, ofuutu fẹẹtẹ lasan ni.

Ẹni ti o jẹ Aarẹ ẹgbẹ awọn darandaran naa, Alhaji Abdullahi Bodejo lo kọkọ sọ fawọn gomina pe ti wọn ba fẹ ki alaafia jọba ni ipinlẹ wọn, wọn gbọdọ fi aaye silẹ fawọn darandaran fun ibugbe wọn.

Amọ, agbarijọpọ awọn gomina ni gbogbo ẹkun mẹrẹẹrin orilẹ-ede yii bu ẹnu atẹ lu awọn darandaran naa pe, ko si ihalẹ ti o le mu wọn yi ipinnu wọn pada.

Awọn gomina ni ko si iru ihalẹ ti o le mu wọn yọnda ilẹ wọn yala fun gbigbe tabi fun ẹran sisin.

Ninu ifesi tirẹ, Aarẹ ana orilẹ-ede Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo sọ pe, aṣisọ ni fun awọn darandaran lati lẹ alaafia orilẹ-ede Naijiria pọ mọ fifun wọn ni ilẹ lati maa gbe.

Gomina Samuel Ortom ti Ipinlẹ Benue ati Darius Ishaku ti Ipinlẹ Taraba ṣalaye pe ofo lasan ni igbiyanju awọn darandaran naa pe ko si ilẹ fun wọn.