Operation Àmọ̀tẹ́kùn: Gani Adams ní OPC àtàwọn míì ṣetán láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò nílẹ̀ Yorùbá

Aarẹ Gani Adams Image copyright Facebook/Aarẹ Gani Adams

Gbogbo awọn agbaagba ninu ẹgbe ajijagbara ẹgbe OPC ati Agbekọya atawọn iru ẹgbẹ bẹẹ mii kaakakiri ilẹ Yoruba ni awọn ti gbaradi bayii lati ṣe iranwọ fawọn oṣiṣẹ eleto aabo kaakiri ilẹ Yoruba.

Aarẹ Gani Adams to jẹ olori OPC tilẹ sọ pe aṣẹ lati ọdọ awọn gomina ipinlẹ Yoruba lawọn n reti lati eto ṣiṣe eto aabo to mọyan lori ti wọn pe orukọ rẹ ni Operation Amọtẹkun.

Akanṣe eto abo yii ni iroyin sọ pe o jẹ ajọmọ ati ajọro gbogbo gomina ni ilẹ Yoruba lojuna ati pese eto abo to peye fun mutun muwa kaakari ilẹ naa.

Ero awọn Gomina yii lo da lori bi ijinigbe ati ipaniyan ṣe wọpọ ni ẹkun naa ti wọn si gbero lati mu opin deba iru iwa buruku bẹẹ..

Ṣe ni nkan bii osu kewa ọdun yii ni wọn gbero lati ko imọ naa jade bi ọmọ tuntun.

Aarẹ Gani Adams ṣalaye pe, ṣalaye siwaju sii pe ''Operation Amọtẹkun'' wa lati ṣekunwọ fun awọn ajọ eleto aabo kaakakiri ilẹ Yoruba

Awọn agbarijọpọ ẹgbẹ ti wọn yoo lo ni ẹgbẹ OPC, Agbekọya, Fijilante, atawọn ẹgbẹ ọdọ ilẹ Yoruba ati ọlọde kaakakiri ileto.

Awọn ẹgbẹ wọnyi ti wa gba lati ṣiṣẹ papọ ti wọn ni wọn si ti kọ iwe si gbogbo Gomina, atawọn olori eleto aabo kaakakiri ilẹ Yoruba.

Agbarijọpọ awọn ẹgbẹ yii ni pupọ ipade ni wọn ti ṣe ni ilu Eko ti wọn yoo si tun ṣe ni ilu Ibadan , ni Ipinlẹ Oyo ni Ọjọru ọsẹ yii.

O ni ko si bi ọrọ eto abo yoo ṣeeṣe laisi awọn irinṣẹ ibanisọrọ to daju. O ni awọn ọkọ ti wa, awọn ọlọpaa si ti wa nilẹ aṣẹ awọn Olọpaa ni wọn duro de.

O ni nigba ti ko ti si Ipinlẹ kan lorilẹ ede yii ti o ni aṣẹ lati ra ohun ija oloro, to si jẹ pe awọn Gomina si ti ṣetan lati ṣe gbogbo ohun amuyẹ lati ra ohun to ba ku.

O wa ṣalaye pe, ko tii si aridaju pe boya ọkọ ofurufu kekere yoo wa lara ohun ti wọn fẹ lo ṣugbọn pe Ijọba Ipinlẹ Ekiti ti ra ọkọ bii ogun silẹ fun eto naa.

Alukoro fun Gomina Ipinlẹ Ogun, Kunle Somorin ṣalaye pe gomina kọọkan ni yoo ko ọkọ ọgọrun silẹ lati bẹrẹ eto naa.