NYSC: O lé wọ sòkòtò tó tobi, sùgbọn kò si àyè fún yẹ̀rì

Agunbaniro Image copyright others
Àkọlé àwòrán Ààye wà fún àgunbanirọ láti wọ sòkòtò lábúlabú- Ọ̀gá àgbà

Ọ̀gá àgbà fún ajọ Agunbanirọ lórilẹ̀-èdè Naijiria, Brig. Shuaibu Ibrahim ti sàlàye fún BBC pé ààyẹ wà fún agunbanirọ to ba fẹ́ wọ sòkòtò to tóbi láti ma fí bi ẹ̀yà ara rẹ̀ ṣe ri han , sùgbọ́n ko si ààyè fún yẹ̀rì.

O ní àwọn alásẹ lé gbójú kurò nínú irú ìmúra bẹ́ẹ̀ sùgbọ́n ko ni fi ojuure wo ẹnikẹni to ba lọ ran síkẹ̀tìì láti fi rópò sòkòtò ti wọ́n pèsè.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÒwò ẹrú ọmọdé àti obìnrin lórí ayélujára

Èyí jẹ́ ìdáhun si ìdí ti wọ́n fi le àwọn agùnbánirọ méjikan ni ìpínlẹ̀ Ebonyi làsìkò ti wan de ìbi ìpàgọ́ ìlànilọ́yẹ ọlọsẹ mẹta ti wọ́n máa n ṣe fun ẹni to ba lọ sìnrú ìlú.

Ìdí ti a ko fi le gba yẹ̀rì

Brig. Ibrahim sọ pé àra ìdí ti awọ ko fi le gbà ki agùnbánirọ wọ síkẹ̀tì ni pé, ko le ṣe yan bí ologun eyí to maa n wáye ni gbogbo igba fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta náà, àti pé ofin àkọsílẹ̀ ni fún ètò agùnbanirọ, èyi si maa n jẹ ki wọ́n ṣe sámusámú

Image copyright NYSC/Twittr
Àkọlé àwòrán Ààye wà fún àgunbanirọ láti wọ sòkòtò lábúlabú- Ọ̀gá àgbà

Oludari ọun ni lóòtọ àwọn ngba ki wọ́n lo Hijabu láti yan bi ologun sùgbọ́n orí àti ọrun nikan lo ń bò.

Ètò agunbanirọ jẹ kànpa fún gbogbo ẹnikẹni to ba kàwé gboye jáde fasiti tabi poli, ti ìwé eri rẹ si jẹ ọkan pàtàkì láti fi wá iṣẹ́ lọ́jọ iwáju, èyí túmọ si pé àwọn meji ti wọ́n lé yìí ko ni ni ànfani láti ṣe iṣẹ́ ìjọba lọ́jọ́ ìwáju, bákan náà ni wan ko le gba ipo ijọba kankan lẹ́yìn wá ọ̀la.

O wá fi kún pé ààye wà fún àwọn méjèèjì láti pada wá ti wọ́n ba setan láti tèlé ìlànà ti àjọ agùnbanirọ̀ là sílẹ̀

Kìí ṣe ìgbà akọkọ rèé ti irú èyí ma n ṣẹlẹ, ni ọdun 2018, wan le Tolulope Ekundayo kuro nio ogba aguibaniro Sah=gamu fun idi kan náà.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lori àtẹjiṣẹ́ twitter ti wa kede pe níwọ̀n ìgbà ti wan ba ti n gba mùsùlùmi láàye láti wọ ijabu nitori ẹ̀sìn, ó pọ́n dàndàn láti gba àwọn oni síkẹ̀ti náà láàye nitori o lodi si ẹ̀sì ti wọ́n náà ni

Image copyright Twitter/NYSC Nigeria

Awọn agunbanirọ meji ni wọn ti fowọ osi juwe ile fun nitori wọn kọ lati wọ ṣokoto ti wọn pese fun wọn ni ipagọ ilanilọyẹ ọlọsẹmẹta nipinlẹ Ebonyi.

Awọn obinrin meji ọun ṣalaye pe ṣokoto wiwọ lodi si ẹsin wọn ti wọn si kọ lati wọọ.

Ninu alaye ti awọn obinrin agunbanirọ naa ṣe, awọn obinrin naa sọ pe nitori igbagbọ lo jẹ ki awọn wọ sikẹẹti dipo sokoto to jẹ alakalẹ ajọ NYSC.

Alukorofun ajọ NYSC nipinlẹ Ebonyi, Ngozi Ukwuoma ṣalaye pe oludari ipagọ, Isu Josephine ri awọn mejeeji nigba ti o n ṣe abẹwo.

Oludari naa ni o fi orukọ awọn mejeeji lede ti wọn n jẹ OkaforLove pẹlu nọmba idanimọ EB/19C/0523 ati Odiji Oritsetsolaye EB/19C/0530.

Ni kete ti wọn mu wọn ni awọn agunbanirọ naa ti ṣalaye pe, awọn ko le wọ ṣokoto funfun pelebe ti ajọ naa fun wọn nitori pe ko ba igbagbọ awọn mu lati wọọ.

Image copyright Twitter. NYSC Nigeria

Gbogbo akitiyan alaṣe ati adari ajọ naa lati mu wọn ri idi ti o fi yẹ fun wọn lati wọ ṣokoto naa lo ja si pabo.

Kete ni ile ẹjọ ti o wa fun awọn agunbanirọ ni ipagọ naa dawọn lebi titapa sofin ati fifi ọwọ pa ida alakalẹ ajọ NYSC loju ti wọn si fi ọwọ osi juwe ile fun wọn lẹyin ọ rẹyin.