Yoruba Film: Damola bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn òṣèré tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì nínú eré Yorùbá

Osere Damola Olatunji Image copyright Damola Olatunji

Ṣe awọn agba bọ wọn ni iṣu atẹnumọ́ràn kìí jóná, eyi lo mu ki awọn oṣere Yoruba kọọkan bẹrẹ si ni tẹnu mọ aṣeju sisọ ede Gẹẹsi ninu ere Yoruba ati fifopin si i.

Gbajugbaja kan lara awọn oṣere Yoruba, Damola Olatunji mu oju opo instagram rẹ pọn lati fi gba awọn akẹgbẹ rẹ ninu ere tiata Yoruba nimọran yii.

O ni "ẹ dakun ẹ jẹ ka dawọ aṣa sisọ ede Gẹẹsi duro ninu awọn ere Yoruba wa tori ede wa ni ami idanimọ wa".

Damola to jẹ ọkọ oṣere Tiata Yoruba mii, Bukola Arugba ṣalaye pe oun mọ wi pe awọn kan le ma fẹran ọrọ ti ou fi sita yii "ṣugbọn mo ṣi maa sọ ọ... ẹ jẹ ka da abo bo aṣa wa".

O sọ siwaju pe idi ti awọn ololufẹ awọn ṣe n wo awọn ere awọn ni wi pe wọn fẹ gbọ ki a maa sọ ede wa, Yoruba. Bẹẹ naa lo si ti n fi awọn ere rẹ kọọkan ṣafihan eyi.

Image copyright @DamolaOlatunji

Bi o tilẹ jẹ wi pe gẹgẹ bi oṣere, oun naa gba pe ọrọ toun sọ ta ba oun gan funra rẹ ṣugbọn awọn kan ṣaa gbudọ dawọ rẹ duro ki wọn si bẹrẹ si ni ṣe ohun to tọ.

"Ẹ jẹ ki fiimu Yoruba wa lede Yoruba ki fiimu Gẹẹsi naa si wa lede Gẹẹsi".

Owe awọn agba ni Damola fi kasẹ ọrọ rẹ nilẹ pe "Omo to ba sọ ile nu, apo iya lo fi kọ ọ".