World Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí

World Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí

Abẹrẹ mẹrin si mẹjọ lojoojumọ nitori itọ ṣuga!- Oluwabunmi

Oni ni ayajọ arun itọ ṣuga ni agbaye eyi ti o n ṣi oju awọn eniyan si ipese itọju to yẹ fun ẹni to ba ni arun yii.

Ayajọ yii tun n jẹ ki awọn eeyan mọ idena ati itọju to yẹ lori arun itọ ṣuga.

Oluwabunmi Adewumi ni arabinrin to mu BBC Yoruba rin irin ajo aye rẹ lati igba to ti ni arun yii lọdun mọkandinlogun sẹyin.

Adewumi mẹnuba ẹru to maa n wa lookan aya ẹni to ni arun yii ati ẹbi rẹ pe ṣe kii ṣe pe ẹni naa ti gba ọjọ iku rẹ ni?

Oluwabunmi sọrọ lori itọju ti oun n gba, o mẹnuba iru ounjé ti o n jẹ ati awọn nkan to n ṣe lati fi mu inu ara rẹ dun laye.

Bakan naa ni Arabinrin yii sọrọ lori awọn idojukọ rẹ ati ipenija ti ẹni to ba ni arun yii n dojukọ lawujọ.

E jẹ ki gbogbo wa ṣe itọju ara wa nitori pe ilera lọrọ ni awọn agba maa n wi.