Nigeria vs Benin: Àwọn ọmọ Nàìjíríà bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu NTA lórí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ wọn

Ileeṣẹ NTA ni papa iṣere Godswill Akpabio lana Image copyright @Ammar_sunkanmi
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ Naijiria bu ẹnu atẹ lu NTA loju opo Twitter pẹlu ami #ShameOnNTA

Awọn ọmọ Naijiria ti fi aidunnu wọn han lori itakunn ayelujara lori bi ileeṣẹ amohunmaworan orilẹ-ede yii, NTA, ṣe ṣafihan ifẹsẹwọnṣẹ laarin ikọ Supper Eagles ati ti Benin lana.

Awọn ọmọ Naijiria bu ẹnu ẹtẹ lu NTA lori bi kamẹra rẹ ko ṣe le yi sọtun ati sosi, ni abala kini ifẹsẹwọnṣe naa.

Bẹẹ na ni wọn tun na ika abuku si ileeẹṣẹ ọhun lataari bi ko ṣe le ṣafihan awọn awọn ohun to ṣe pataki lẹẹkeji fun awọn onworan to wa nile.

Bakan naa, wọn ni igbohunsafẹfẹ ti NTA ṣe lori ifẹsẹwọnṣe ri balabala, ti ko si ṣe e wo.

Idi eyii lo mu ki awọn ọmọ Naijiria bu ẹnu ẹtẹ lu ileeṣẹ naa loju opo Twitter pẹlu ami #ShameOnNTA.

Royal beere pe, "Nigba wo ni ileeṣẹ NTA yoo ṣatunṣe si igbohunsafẹfẹ wọn?"

Obinna Nwosu ni ti ẹ ni, ileeṣẹ NTA ko ni idagbasoke kankan lati ogun ọdun sẹyin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí

Olajuwon sọ pe, oun yoo yan lati wo ifẹsẹwọnṣẹ lori ẹrọ asọrọmagbesi kaka ki oun wo lori ẹrọ NTA.

Ẹ wo ohun tawọn ọmọ Naijiria mii n sọ loju opo Twitter.

"Aug 2018 ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ APC ti ṣe ìpàdé kẹ́yìn, Oshiomole ti kùnà"

Ọ̀pọ̀ àwòrán rèé tó ń sàfihàn bí Ibadan se kún fún ẹ̀gbin àti òórùn

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAeroplane House: Látọdún 1999 ni mo ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé yìí fún ìyàwó mi ọ̀wọ́n

Bẹẹ, loju awọn miran, wọn ni o ṣeeṣe ko jẹ pe NTA ko tete mọ pe awọn maa gbe idije naa ki wọn le pese awọn nkan ti wọn nilo.