Nigeria Bad roads: Àwọn obìnrin abúlé yìí ń pàdánù ọmọ látàrí òpópónà tó mẹ́hẹ

Abule Madaka Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Awọnn eeyan naa ma n koju iṣoro pupọ ki wọn la oriṣiriṣi odo kọja

Ti ọjọ ikunlẹ alaboyun ba de, idunnu ati ayọ lo maa n jẹ, ṣugbọn ko ri bẹẹ fun awọn olugbe abule Madaka ni ipinlẹ Niger ni aarin gbungbun Naijiria.

Ọpọ awọn alaboyun lo ti gbẹmi mi ni ilu naa ti wọn ba fẹ bimọ, nitori ko si opopona lati gbe wọn lọ si ile iwosan.

Opopona kan ṣoṣo lo so ijọba ibilẹ Kagara pọ mọ ilu Madaka mọ awọn abule to ku.

Opopona yii lo ja mọ abule Mgwa Magaba, Kompani, Rubo, Nafsira, Shikira, ati Wayam papọ mọ ara wọn.

Ipinlẹ Niger jẹ ọkan lara ipinlẹ ti a da silẹ lọdun 1976.

O ni awọn ilu nlanla bii Minna, Bida, Suleja, Kotongora atawọn ilu miran.

Àkọlé àwòrán Okan ninu awon odo naa niyi ti o ni lati sanwo fawon odo lati ba e ru alupupu re koja odo

Ni nkan bii 1800 ni awọn oyinbo amunisin ti gbe ni agbegbe Madaka nitori pe goolu pọ nibẹ ki wọn to kuro lọdun 1946 nigba ti goolu di ọpọ yanturu kaakiri.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Awọpn obinrin Madaka sọ pe aye wọn ninu ewu latari ọna ti ko si

Hajara Kadamato, to jẹ ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ si sọ pe, oun padanu ọmọ nitori ọna ti ko si labule ọhun.

O ṣalaye pe, bi oun ṣe n rọbi lọwọ ni wọn gbe oun sori alupupu, ṣugbọn ki wọn to de ile iwosan ni ọmọ naa di ologbe si oun ninu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí

O ni wọn gbe oun lori timutimu lati kọja odo mẹrin lati ile ki wọn to de ile iwosan ọhun.

Hajara sọ siwaju si pe, wahala lati kọja odo ati ọna ti ko dara lo fa ṣababi bi oun ṣe padanu ọmọ oun.

Àkọlé àwòrán Àwọn obìnrin abúlé yìí ń pàdánù ọmọ látàrí òpópónà tó mẹ́hẹ

Hajara ni, oun ko ti i bi ọmọ mii lati igba ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ, to si jẹ ibanujẹ nla fun oun.

Kini idi ti awọn alaboyun fi n ku ninu odo wọnyii?

Odo Alhaji Bako, Luga, Wayam ati Nafsira ni odo mẹrin ti wọn n gba kọja lọs i ile iwosan ni eyi ti ko si afara lori ikọkan ninu wọn.

Àkọlé àwòrán Góòlù pọ̀ ní ìlú Madaka ṣùgbọ́n wọn kò ní ọ̀nà fún ọgọ́rùn ún ọdún

Fred Achem to jẹ dokita obinrin naa sọ fun BBC pe, bi awọn alaboyun ṣe n ngba inu odo kọja, wọn le fara ko aisan, eyi to maa n ṣe ijamba fun ọmọ inu.

Dokita naa sọ pe ohun gbogbo lo wọn gogo lagbegbe naa, latari ọna ti ko si, bẹẹ si ni awọn aboyun maa n ri eemọ ki wọn to bimọ.

Àkọlé àwòrán Agbe parawu ni awon eniyan Madaka n se ni eyi ti won kii tete ri awon ire oko won gbe lo ta loja nlanla

O ni apo ile ọmọ wọn le ja tabi ki wahala irora wiwẹ tabi gbigbe wọn lori odo to maa n ṣakoba aile tete ṣe iṣẹ abẹ fawọn to nilo rẹ ti wọn ba gbe wọn de ile iwosan.

Àkọlé àwòrán Àwọn olùgbé Madaka ní ìpínlẹ̀ Niger ṣàlàyé ìsòro tí wọ́n ń dojúkọ fún BBC látàrí àìsí òpópónà gidi.

Kini ijọba ti ṣe fun awọn eniyan abule yii?

Igba kan ṣoṣo ni ijọba ti gbiyanju lati la ọnade agbegbe yii ni ipinlẹ Niger ni lọdun 1985.

Abdullahi Usman Kantago to jẹ oloye pataki ni abule yii ṣalaye fun Dooshima Abu, akọroyin BBC pe awọn ologun ni wọn gbiyanju ọna naa ṣugbọn wọn ko da ọda sii.

Ati pe titi di isinyii, ko tii si ijọba to wẹyin wọn wo.