Àìsàn ìtọ̀ súgà kò túmọ̀ sí pé èèyàn ti gba ọjọ́ ikú- Dókítà

Wilson Ikubese Image copyright facebook/wilson ikubese
Àkọlé àwòrán Aisan itọ ṣuga ma n jina rere si ẹni to ba n ṣe ere idaraya

Wilson Ikubese, to jẹ dokiita ati onimọ nipa eto ilera ti sọ pe, aisan itọ suga ko tumọ si pe eeyan ti gba ọjọ iku

Ikubese lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC layajọ aisan itọ ṣuga tọdun 2019, eyi ti gbogbo agbaye n ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí

O sọ pe, ẹni to ba ni aisan yii le jẹ iru ounjẹ ti ẹni ti ko ni aisan naa n jẹ, ṣugbọn, ko jẹ ẹ ni iwọntuwọnsi.

Dokita naa gba awọn ti aisan itọ ṣuga n ba finra lamọran pe, ki wọn ṣọra fun awọn ounjẹ amunukun ati ọti mimu.

O ni ki iru ẹni bẹẹ ma jẹ ounjẹ aṣaraloore.

Lori boya aisan itọ ṣuga le ran ẹlomiran, o ni ko ṣeeṣẹ ki aisan naa ran ẹlomiran.

Fun ẹni ti ko ni aisan ṣuga, dokita Ikubese sọ pe ki iru ẹni bẹẹ ṣọra fun ara sisan, ko si ṣọra fun ounjẹ jijẹ lẹyin aago meje aṣalẹ.

Dokita ọhun tun ni, aisan itọ ṣuga ma n jina rere si ẹni to ba n ṣe ere idaraya.

Ikubese pari ọrọ rẹ pe, ko ti si ogun ibilẹ to le wo aisan itọ ṣuga san patapata.

Bẹẹ lo rọ ẹni to ba n lo ogun iblẹ funn aisan ṣuga lati ma lo papọ pẹlu ogun oyinbo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAeroplane House: Látọdún 1999 ni mo ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé yìí fún ìyàwó mi ọ̀wọ́n