Hate speech: Ero wa kò yípadà lórí àbádòfin ìṣàkóso ẹ̀rọ ayélujára - Lai Mohammed

Lai Mohammed Image copyright @first_reports
Àkọlé àwòrán Afojusun ijọba ni awọn to n lo opo ikansiraẹni lati fi sọrọ ikorira

Ijọba apapọ ti sọ pe, oun ki yoo boju wẹyin lori aba lati ṣakoso opo ikansiraẹni lori itakun agbaye.

Minisita fun iroyin, ifitonileti ati aṣa, Lai Mohammed lo sọ ọrọ naa fun awọn akọroyin.

O ni, ijọba apapọ ko ni yi ipinnu rẹ pada lori abadofin naa bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ Naijiria n bu ẹnu ẹtẹ lu ijọba nitori ọrọ ọhun.

Mohammed ni erongba ijọba apapọ ki n ṣe lati fi ẹtọ awọn Naijiria lati sọrọ du wọn, ṣugbọn o jẹ ọna lati fọ ori itakun ayelujara mọ.

O sọ pe "Afojusun wa ni awọn eeyan to n lo opo ikansiraẹni lati fi pin iroyin ẹlẹjẹ ati ọrọ ikorira, leyi to lewu fun irẹpọ wa gẹgẹ bi orilẹ-ede kan."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDivorcee: Ó sàn kí wọ́n yàgò fúnra wọn ju ki wọ́n ṣe ara wọn léṣe- Fisayo

Lai Mohammed tẹsiwaju pe "Ko si ijọba kankan to ni ifẹ ara ilu lọkan ti yoo faaye gba ki awọn eeyan maa sọrọ ikorira, ki wọn si tun maa pin iroyin eke lori itakun agbaye."

O ni kii ṣe Naijiria ni orilẹ-ede akọkọ ti yoo ṣofin iṣakoso opo ikansiraẹni lori itakun agbaye.

Minisita naa darukọ awọn orilẹ-ede mii lagbaye to n ṣakoso bi awọn eeyan wọn ṣe n lo ẹrọ ayelujara, bi Singapore, China, South Korea, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí