Àwujọ ẹ rọra ṣe ìdájọ́ ẹni tó kọ ọkọ / aya sílẹ̀ nítorí pé kò wùú- Odumosu
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Divorcee: Ó sàn kí wọ́n yàgò fúnra wọn ju ki wọ́n ṣe ara wọn léṣe- Fisayo

Oju wo lẹyin gan an fi n wo ẹni to kọ aya / ọkọ rẹ silẹ?

Ọpọlọpọ igba ni ọrọ lọkọ laya kii ye ara wọn mọ ti o maa n di ija lojoojumọ lọọdẹ wọn.

Awọn kan gba pe ko to di pe wọn a pa ara wọn sinu ile, o san ki onikaluku ko ẹkọ ẹ dani ṣugbọn awọn miran gba pe ko si ohun ti suuru ko le ṣe.

Arabinrin Fisayo Alabi ati Ogbẹni Wale Odumosu ti wọn ti kọ ọkọ ati aya wọn silẹ ni wọn sọrọ nipa iriri wọn ninu agodo BBC Yoruba.

Awọn mejeeji fidiẹ mulẹ pe ọgbẹ ọkan to tobi ni ikọra ẹni silẹ jẹ fun ẹda nitori ko si ẹni to wu lati maa da gbe inu ile rẹ.

Awon mejeeji fẹnuko pe ki awujọ rọra ṣe igajọ awọn ti wọn ti kó ara wọn silẹ nitori kọrọ aye san ju agbala ọrun lọ ki lọkọlaya ma lọ ṣe ara wọn leṣe.