Kogi 2019 Election: Olùdíje 24 ni yóò kópa ní ìdìbò Kogí

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Gomina ìpínlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello láti inú ẹgbẹ́ òsèlú APC náà ń kópa nínú ìdìbò sípò gómìnà náà.

Ẹgbẹ oselu APC ati PDP lo jẹ gboogi ninu ẹgbẹ oselu mẹrinlelogun to n kopa ninu idibo sipo gomina ni ipinlẹ Kogi.

Ajọ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria ti ko awọn ọlọpaa to to 35,000 sita lati rii wi pe eto aabo to peye wa fun idibo naa ni oni ọjọ kẹrindinlogun, Oṣu Kọkanla, ọdun 2019.

Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello lati inu ẹgbẹ oselu APC naa n kopa ninu idibo sipo gomina naa.

Bello ni gomina to kere julọ lorilẹ-ede Naijiria.

Idibo yii ni yoo fihan boya awọn eniyan fẹran rẹ nitori ọpọlọpọ igba ni awọn eniyan ti bu ẹnu atẹ lu aisan owo oṣu awọn osisẹ ni ipinlẹ naa.

Ninu awọn to n dije dupo ọhun ni Musa Wada lati ẹgbẹ oselu PDP ti o tẹle ipase ẹgbọn rẹ, Idris Wada.

Musa lasiko ipolongo rẹ so wi pe, ti wọn ba dibo fun oun, oun yoo san gbogbo owo osu osisẹ ti wọn jẹ wọn ati gbogbo owo ajẹmọnu awọn osisẹ.

Natasha Akpoti to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji to n dije dupo labẹ ẹgbẹ oselu SDP, ko fi pamọ wi pe oun ko gba ti gomina Yahaya Bello naa.

Bi o tilẹ jẹpe Dino Melaye ko dije dupo nitori o kuna ni idibo abẹle, ọpọlọpọ eniyan ni oun tẹle lori opo ikansiraẹni Twitter rẹ.

E wo bi wọn se pin ipinlẹ Kogi

  • Ila Oorun Kogi lo tobi julọ ni ipinlẹ naa, ti o si ni iye awọn eniyan to to 804,715, amọ ti eniyan 1,646,350 fi orukọ silẹ fun idibo ni ipinlẹ naa.
  • Ẹkun idibo mẹsan ninu mọkanlelogun lo wa ni Ila Oorun Kogi, amọ a ko le e sọ wi pe ẹni to ba jawe olubori ni Ila Oorun Kogi ni yoo bori ninu idibo sipo gomina naa.
  • Oye awọn eniyan to fi orukọ silẹ ni ẹkun gbungun Kogi nibi ti gomina Yahaya Bello ti wa ni 409,120 pẹlu ẹkun idibo marun un.
  • Ẹkun Iwọ Oorun Kogi ni iye eniyan to to 432,515 to forukọ silẹ fun idibo naa ni pẹlu ẹkun idibo meje.

Bi idibo yoo se lọ

  • Ajọ Eleto Idibo, INEC ti ni aago mejọ aarọ si meji ọsan ni wọn ni ayẹwo orukọ yoo pere ni pẹrẹwu.
  • Ẹni ti o ba de agọ idibo ki aago meji ọsan to lu ni wọn yoo fun laaye lati dibo.
  • Kaadi idibo ni wọn yoo lo lati fi se idibo naa.
  • Osisẹ Ajọ INEC yoo pere kaadi idibo rẹ lati se ayẹwo orukọ rẹ boya o fi orukọ silẹ.
  • Wọn ti kilọ fun awọn eniyan lati fi ago idibo silẹ ni kete ti wọn ba ti dibo wọn tan.
  • Ko gbọdọ si lilo ẹrọ ibanisọrọ ni ayika ibi ti idibo ba ti n lọ lọwọ.