Efe DELSU: Ọlọpàá gba owó ilé ìwé lọ́wọ́ akẹ́kọọ DELSU

Image copyright Police.ng
Àkọlé àwòrán Ọlọpàá gba owó ilé ìwé lọ́wọ́ akẹ́kọọ DELTSU

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ ọsẹ̀ ni àwọn obí Efe Ifie fi ń sá hílahilo láti fún ọmọ wọn ni owó ilé iwé rẹ̀ ki gbèndeke oṣù kejila ti wọ́n dá to pé, aṣẹyìn wá àṣẹ̀yin bọ, wọ́n fi owo náà ránṣẹ́ si ilọ́jọ Ajé.

Efe Ifie to wá ni ipele kẹta ẹkọ imọ̀-ẹ̀rọ ni Fasiti ipinlẹ Delta gbẹ́ra lati lọ gba owó náà to si morile ilé iwé rẹ̀ lọ́sàn ọjọ náà.

Efe ni, ni kété ti àwọn rin kìlómita díẹ̀ kúrò ni òpópónà Sapele si Warri ni àwọn ri ibudo ayẹwo àwọn ọlọpàá ti awákọ àwọn si dúro, ní àwọn ọlọpàá to ni gbogbo ìhàmọra ba gbà ẹgbẹ̀run lọ́nà ààdọjọ Naira to yẹ ki oun fi san owó ilé ìwé òun.

O ní wàhàlà náà bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ti wọ́n dá ọkọ àwọn dúró tan ti wọ́n ni ki gbogbo àwọn sọ̀kalẹ̀, ni wọn ba bẹ̀rẹ̀ si ni tú báàgì wọn, sùgbọ́n wọ́n kò rí ǹkankan to le dàbi àkobá, ọ̀kan nínú wọ́n si gba fóònù oun.

"Nígbà to bẹ̀rẹ̀ sí ni wòó, o rí àpò iwé ayelujara (Gmail) méji "o ní òun sọ fun wọ́n pé ọkàn wà fún òun èyí ti o jẹ́ orúkọ ti ẹ̀ nígbà ti ìkeji jẹ ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ijó òun.

Ẹni ọdún méjìlélógun òhun ni, ǹkan to ya oun lẹ́nu jùlọ ni pe, ọlọpàá náà ni gbájúẹ̀ orí ayelujara ni òun nítori pé òun ní àpò iwé ayelujara meji lórí fóònù, wọ́n si fi paǹpẹ si oun lọ́wọ, wọ́n si sọfun awakọ èrò náà pe kí o máà lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí

Akẹkọọ yii ni: wọ́n mú mi lọ si ọgba ọlọpàá ni ǹkan bii ààgo méji ọsàn, mo bẹ̀ wọ́n ki wọn jẹ ki n pe àwọn obí mi nítori pé àkẹkọọ ni mi àti pé mọ ń lọ sí ilé ìwé ni.

Sugbọn wọ́n ni alátiṣe mi ni yóò mọ atiṣe ara rẹ, mo bèèrè ìtùmọ ǹkan ti wọ́n sọ, wọ́n bèèrè bóya mo ni owó lọ́wọ́, mo ni rára, wọ́n bẹ̀rẹ̀ si ni tú fóònu mi, wọn ri ẹgbẹ̀run lọ́nà ìgbà náira níbẹ̀.

Efe ni wọ́n bèèrè ìlú ti òun ti wa ti oun si sọ fun wọ́n pe Urobo, wọ́n ni olé ni àwọn Urobo nitori náà ẹgbẹ̀run lọ́nà ààdọjọ naira ni owó ìtànran mi tí ǹ ko bá si sàn an àwọn yóò ju mi si ẹyin kanta bi àwọn ẹgbẹ́ mi to ti wà níbẹ̀ láti ọsẹ̀ méji sẹ́yìn.

O sàlá[yé pé òun rọ wọ́n láti jẹ́ ki òun pe òbí òun sùgbọ́n wọ́n kọ, àṣẹyinwá àṣẹ̀yìnbọ, wọn mu oun lọ si idi ẹrọ to n pọ owo sùgbọ́n ko siṣẹ́ ni wọn wá wá lọ POS kan ni àyíka agọ ọlọpàá náà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDivorcee: Ó sàn kí wọ́n yàgò fúnra wọn ju ki wọ́n ṣe ara wọn léṣe- Fisayo

Odọmọkunrin yii ni: "Wọn gbe àpò mi àti fóònù pe kí n maa lọ, ọlọpàá míràn tun ri mi pé ki oun má gba ọna ibi ti òun fẹ́ gbà nítori ti àwọn míràn ba tun ri òun, wọ́n a mú oun pada wá ti yóò si san owo míràn.

Awọn obi rẹ ti n gbe igbese lori ọrọ naa ti wọn si n pariwo sita pe eyi ku diẹ kaa to lawujọ wa.