Ghana Health: Ikú ni fífi oògùn 'Paracetamol' bọ ẹran- Iléeṣẹ́ ìlera

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán E dekun fifi oogun ara riro Paracetamol se ewa tabi fi bo eran ko le tete ro- ileese ilera

Ileeṣẹ to n risi ilera awon eniyan orilẹ-ede Ghana ti ke gbajare sita pe ki awọn eniyan ṣọra fun lilo oogun ara riro fi bọ ẹran tabi se ẹwa ko le tete rọ.

Wọn ni lilo oogun paracetamol yii ni ewu to pọ.

Obed Sefah Boakye to jẹ oṣiṣẹ agba ni ile iwosan ijọba Wassa Akropong Government Hospital lo ṣalaye pe to ba ya oogun ara riro yii ko nii ṣiṣẹ mọ.

O ni atunbọtan lilo oogun ara lilo bayii maa n di nkan miran ni to dẹ maa di majele sara awọn to n jẹ iru ounjẹ yii.

Obed salaye pe majele ti oogun ara riro maa n pada di ninu ẹran ati ẹwa sise le fa ki kindinrin eniyan kọ iṣẹ tabi ki fuku, oronro ati ọkan eniyan kọ iṣẹ silẹ.

O ni iku lo dẹ maa gbẹyin awọn iṣẹlẹ ki ẹya ara eniyan kan deede kọ iṣẹ silẹ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLábẹ́ odò! Ìgbéyawó yìí lárinrin

Awọn iwe iroyin ilẹ Ghana kan lo kọkọ gbee sita pe awọn alase kan n fi oogun ara riro paracetamol se ounjẹ ko le tete rọ daadaa.

O wa paṣẹ pe ki onikaluku lọ ṣọra fun ounjẹ ti wọn n jẹ ki aisan ati arun to lagbara ma ti ibi ounjẹ wọ agọ ara ẹni.