Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá di ẹ̀bi rògbòdìyàin ní Kogi ru ìwà kòtọ́ àwọn olóṣèlú

Awọn oludibo lẹyin tawọn janduku wa da ibo agbegbe kan ru ni ipinlẹ kogi

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ko din ni eeyan mejilelogun ni ọwọ ti tẹ lori rogbodiyan to waye lasiko idibo nipinlẹ Kogi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba lo ṣalaye ọrọ yii lasiko to fi n sọrọ lori ileeṣẹ mohunmaworan abẹle kan lorilẹede Naijiria lalẹ ọjọ Satide lẹyin ti ibo didi pari lawọn ipinlẹ mejeeji.

Bakan naa lo ni ọkọ kan tawọn janduku fẹ fi lọ hu iwa laabi wọn lagbegbe kan ni Kogi lọwọ awọn ọlọpaa tun tẹ.

O fi kun pe oniruuru ibọn pẹlu ọkẹaimoye ọta ibsn ni wọn tun gba lọwọ awọn ọdaluru kan nipinlẹ naa.

Ọga ọlọpaa Frank Mba ni awọn oloṣelu pẹlu iwa booba o pa, boo ba o bu u lẹsẹ ati iwa afemi-afemi wọn lo fa gbogbo rukerudo to waye lasiko idibo ni ipinlẹ mejeeji, paapaajulọ nipinlẹ Kogi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ko si aniani pe eto idibo gomina nipinlẹ Kogi gbomi lara awọn agbofinro ju ti ipinlẹ bayelsa lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ni lootọ ni awọn ṣe ifimufinlẹ to munadoko ṣaaju idibo naa lati ms ibi ti eefin wahala lee ti ru lasiko idibo naa sibẹ ohun to waye kii ṣe eyi ti wọn lee maa dẹbi rẹ ru awọn agbofinro bi o ti wulẹ o mọ. O ni ka ni kii ṣe bẹẹ ni, ohun ti o ṣẹlẹ ko ba buru ju bi o ti ri naa lọ.

Nigba to n dahun ibeere lori iye eeyan to ku lasiko idibo ni ipinlẹ Kogi, lẹyin ti iroyin fi idi rẹ mulẹ pe eeyan mẹta lawọn afunrasi janduku kan ti wọn wọ aṣọ ọlọpaa yinbọn pa lasiko idibo naa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria naa ni oun ko tii le sọ ni pato iye awọn eeyan to padanu ẹmi wọn lasiko idibo naa.