Kogi 2019: Wada takò èsì ìbò Kogi, o fà Alága INEC àti ọgá ọlọ́pàá lè Ọlọrun lọ̀wọ́

Aworan Musa Wada Image copyright Facebook/Musa-Wada-for-Governor-Kogi-

Ninu atẹjade to fi tako esi idibo naa, Wada sọ pe inu ibẹru lawọn eeyan Kogi fi dibo ati pe niṣe lawọn ajọ eleto idibo ati ọlọpaa gbimọranpọ lati da ibo ru.

Oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo ipinlẹ Kogi ni oun fa alaga ajọ eleto idibo ati ọga ọlọpaa le Ọlọrun lọwọ fun ipa ti wọn ko ninu idibo naa.

Musa Wada to ṣe ipokeji ninu idibo naa sọ ọrọ yi ninu atẹjade kan to fi sita lẹyin ti ajọ eleto idibo INEC kede Yahaya Bello ti ẹgbẹ oṣelu APC lẹni to pegede ninu idibo naa.

Wada ni iditẹgbajọba ni ohun to ṣẹlẹ lasiko idibo naa ti o si na ika abuku sawọn ọlọpaa ti wọn gbimọran pẹlu awọn janduku lati da ibo ru.

''Awọn ọlọpaa ran awọn janduku lọwọ lati ji apoti ibo gbe, yinbọn lu ara ilu ti wọn si kọ esi ibo to wu wọn eleyi ti ajọ INEC ba wọn gbe sita''

Wada tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe inu fu aya fu lawọn eeyan Kogi wa lasiko idibo naa ti awọn eeyan si wa ninu ẹkun ohun oṣe lati igba ti wọn ti kede pe APC lo jawe olubori.

O fi kun ọrọ rẹ pe alaga ajọ eleto idibo to dari idibo naa, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ati ọga agba patapata ọlọpaa ni Naijiria, Mohammed Adamu yoo jabọ ipa ti wọn ko ninu idibo naa niwaju Ọlọrun ati awọn eeyan ipinlẹ Kogi.

Wada fidirẹmi ninu idibo naa pẹlu ibo 189,704 si Ibo 406,222 ti Yahaya Bello to jẹ oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ni.

Wada ni kawọn eeyan ipinlẹ Kogi ma foya ki wọn si ma sọ ireti nu nitori oun yoo lọ si iwaju igbimọ to n gbẹjọ esi idibo lati tako esi idibo ohun.

Titi di bi a ti ṣe n ṣakojọpọ iroyin yi,ileeṣẹ ọlọpaa ati ajọ eleto idibo ko ti fesi si ọrọ Wada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÓ di dandan kí ará India yìí sọ ìdí tó fi ń sìn kìnìhún- Egbeyemi

PDP, SDP ta ko ìdìbò ipò sẹ́nétọ̀ ẹkùn Ìwọ̀-òòrùn Kogi

Dino Melaye: Ìdìbò orí òfúrufú ni ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Kogi.

Ọjọ́ Kẹtàdínlógún, Osu Kọkànlá, ọdún 2019 ni ìdìbò sípò gómìnà àti àtúndì ìdìbò sípò sẹnétọ̀ wáyé ní ìpínlẹ̀ Kogi.

Oludije ti ẹgbẹ oselu PDP sipo sẹnatọ ni ẹkun Iwọ-ooorun ipinlẹ Kogi, Dino Melaye ti ni ko si otitọ kankan ninu idibo to waye ni ipinlẹ Kogi naa.

Melaye to ba awọn akọroyin sọrọ ni Abuja sọ wi pe , iwa ipa, magomago ati iwa jẹgudujẹra to waye ni idibo sipo sẹnatọ ọhun.

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ Kẹtàdínlógún, Osu Kọkànlá, ọdún 2019 ni ìdìbò sípò gómìnà àti àtúndì ìdìbò sípò sẹnétọ̀ wáyé ní ìpínlẹ̀ Kogi.

O ni awọn asebajẹ tun lo ọkọ ofurufu lati ṣe magomago ninu idibo naa, eleyii ti o ni iru rẹ ko ṣẹlẹ ri.

Melaye ni iwa ipa ati jagidijakan to ṣẹlẹ ni agbeegbe oun to fun Ajọ INEC lati gbegile eto idibo naa.

Ọjọ Kokanla, Osu Kẹwa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun pasẹ ki ajọ eleto aabo ṣe atunṣe ibo ni ẹkun Iwọ oorun Kogi laarin Sẹnatọ Dino Melaye ti ẹgbẹ oṣelu PDP ati sẹnatọ Smart Adeyemi ti ẹgbẹ oselu APC.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKogi vs Bayelsa: Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀

SDP náà tako idibo sipo gomina ni ipinlẹ Kogi

Oludije sipo gomina lẹgbẹ oselu SDP ni ipinlẹ Kogi, Natasha Akpoti ti ni ki ajọ eleto idibo Naijiria, INEC fagile eto idibo gomina to waye ni ipinlẹ Kogi.

Akpoti sọ eyi lasiko to tako eto idibo sipo gomina to waye ni ipinle kogi.

O ni irọ lasan ni idibo naa, paapa ni ẹkun Iwọ-oorun Kogi, nitori iwa ipa ati jagidijagan ni agbegbe naa ko jẹ ki awọn eniyan ko dibo.

Oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu SDP to wa lati ẹkun idibo kan naa pẹlu gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello sọ wi pe awọn onijagidijagan ẹgbẹ oṣelu APC lo wa ni idi rogbodiyan to waye ni agbeegbe naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àwa akódọ̀tí táà ń gba £1,500 lóṣù níbi sàn ju Sẹ́nétọ̀ lọ ní Nàìjíríà'