Lagos Lion: A kò fẹ́ kìnìhún ni àdùgbò wa mọ́- àwọn olùgbé V. I. ní Eko yarí

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÓ di dandan kí ará India yìí sọ ìdí tó fi ń sìn kìnìhún- Egbeyemi

Lọjọ Eti to kọja ni àwọn eniyan agbegbe Muri Ọkunola ni Victoria Island ni ipinlẹ Eko ni guusu Naijiria yari pe o to gẹẹ, lati maa ba kinihun gbe ni adugbo.

Saaju ni wọn ti kọkọ kọwe si ajọ to n mojuto atunṣe agbegbe ati awọn iṣẹlẹ ọdaran to yatọ iyẹn Lagos State Environmental Sanitation & Special Offences (Enforcement Unit) LASESSO.

Lati ọjọ Eti ni ajọ LASESSO ti wa ni iwaju ile ọkunrin ara orilẹ-ede India ti wọn ni o n sin kinihun yii.

Ogbéni Yinka Odeyemi to jẹ adari wọn ṣalaye pe kọmiṣọnna fun ọrọ awujọ ati iṣẹ agbẹ ti fun wọn laṣẹ lati gun kinihun naa ni abẹrẹ to maa gba agbara rẹ loni.

Àkọlé àwòrán Ile iwe awon omode to wa legbe ile ti okunrin naa ti n sin kinihun ni Victoria Island.
Àkọlé àwòrán Lagos Lion: A kò fẹ́ kìnìhún ni àdùgbò wa mọ́- àwọn olùgbé V. I. ní Eko yarí

A kò fẹ́ kìnìhún ni àdùgbò wa mọ́- àwọn olùgbé V. I. ní Eko yarí

Arakunrin India yii ni wọn fẹsun kan pe o n sin kinihun ti kii ṣe ẹran ọsin ninu ile ninu ile rẹ to wa lẹgbẹ ile iwe awọn ewe ni Victoria Island.

Egbeyemi ni wọn ti ri kinihun naa ni ojule 229, adugbo Muri Okunola ni Victoria Island.

Àkọlé àwòrán okan lara ile iwe ti o wa ni adugbo ti kinihun yii n gbe niyii

Awọn oṣiṣẹ atunṣe awujọ ti wa ni ikale niwaju ile naa lati mu aṣẹ kọmiṣọnna ṣe bayii.

Egbeyemi fidiẹ mulẹ pe o ṣeese ki wọn pe arakunrin ara India naa lẹjọ fun sinsin kinihun ninu ile bi ẹran ọsin.

Àkọlé àwòrán Awon ileese yii ti setan lati pese abbo to ye fun awon olugbe adugbo ti kinihun yii wa

Koda wọn ti wa pẹlu awọn ọkọ ti wọn yoo fi gbe kinihun naa ti wọn ba ti gun un ni abẹrẹ ti yoo gba agbara rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi

Wọn ni arakunrin ọmọ India yii gba ile naa lọwọ onile pe oun fẹ maa gbe ibẹ ni

Àkọlé àwòrán Oko Black Maria ti won fe lo lati fi gbe kinihun yii kuro ninu ile naa ti wọn ba ti gun un labẹrẹ tan

Arakunrin India yii wa ni oun n ṣe atunṣe to yẹ fun ile naa ni o ba gbe kinihun kan wọnu ibẹ.

Àkọlé àwòrán Awon osise eleto aabo ti duro wamu lenu ona ile naa lati gbe igbese to ye

Bayii ti ile iṣẹ BBC ti de si ile yii ni wọn ti ri awọn agbofinro ati awọn eniyan ti wọn duro siwaju ile naa lati mu aṣẹ Kọmiṣọnna ṣẹ.

Àkọlé àwòrán Ase lati odo ijoba ni yii ti iko BBC ba lenu ona ile naa

Kete ti awọn akọroyin BBC de iwaju ile naa ni wọn ti ba iwe aṣẹ ijọba ti wọn fi paṣẹ igbese ti wọn fẹ gbe fun ọkunrin ara India yii.

Àkọlé àwòrán Iloro enu ona ibi ti okunrin naa fi kinihun naa si ni yii

Awọn ara adugbo lo ri kinihun naa ti wọn si gbọ iro rẹ ki wọn to kọwe ranṣẹ si ajọ naa.

Ogbeni egbeyemi ni o di dandan ki ọkunrin India naa ṣalaye idi to fi n sin kinihun gẹgẹ bii ẹran ọsin laarin ilu

Àkọlé àwòrán Kinihun naa to di eranọsin inu ile ni Victoria Island ni yii
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood:Ṣàgbẹ̀lójú yòyò ni ọ̀ps àwọn òṣèré- Ojopagogo
Àkọlé àwòrán Won ti n sise lori kinihun naa

Egbeyemi tun ṣalaye pe ijọba maa fẹ mọ ibi ti arakunrin India yii ti ri Kinihun naa gbe wa si adugbo ọhun.

Wọn ti ri kinihun naa gbe lọ si ọgba ẹlẹranko Omu ni Bogijẹ ni Lekki.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKogi vs Bayelsa: Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀

BBC yoo maa mu bi o ba ṣe n lọ wa fun un yin loju opo yii