Wo bí wọ́n ṣe gbé Kinihun tí ará India n sìn ni Eko!
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lagos Lion: Ó di dandan kí ará India yìí sọ ìdí tó fi ń sìn kìnìhún- Egbeyemi

Awọn oṣiṣẹ alatunṣe agbegbe ni ìpínle Eko, Lagos Environmental Sanitation & Special Offences ti dé si ilé ọkùnrín India to n sin kinihun ni V.I.

Bawo ni ọrọ kinihun yii ṣe jẹ? Ó di dandan kí ará India yìí sọ ìdí tó fi ń sìn kìnìhún- Egbeyemi àti pe Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé Cameroon ni wọ́n ti ru Kìnìhún VI wá?

Arakunrin India ni wọn no o gbe kinihun yii wole ni ojule 229, adugbo Muri Okunola ni Victoria Island.

Saaju ni wọn ti kọkọ kọwe si ajọ to n mojuto atunṣe agbegbe ati awọn iṣẹlẹ ọdaran to yatọ iyẹn Lagos State Environmental Sanitation & Special Offences (Enforcement Unit) LASESSO.

Lati ọjọ Eti ni ajọ LASESSO ti wa ni iwaju ile ọkunrin ara orilẹ-ede India ti wọn ni o n sin kinihun yii.

Ogbéni Yinka Odeyemi to jẹ adari wọn ṣalaye pe kọmiṣọnna fun ọrọ awujọ ati iṣẹ agbẹ ti fun wọn laṣẹ lati gun kinihun naa ni abẹrẹ to maa gba agbara rẹ loni.

Ni eyi to ti wa si imuṣẹ bayii.

Bayii wọn ti gbe kinhun naa lọ si ọgba eranko ni Omu ni Bogijẹ ni Lekki.

Ogbeni Egbeyemi ti ni arakunrin India yii ni lati wa wi tẹnu rẹ lori ọrọ kinihun naa to sọ di ẹran ọsin ile laarin igboro.