Lagos Lion: BBC ṣèwádìí ibi tí aráa India tó ń sin Kìnìhún wà

Kinihun VI

Adari igbimọ amuṣẹya fun ajọ alatunṣe agbegbe ni ìpínle Eko, Lagos Environmental Sanitation & Special Offences, Yinka Egbeyemi salaye fun BBC Yoruba pe awọn n reti olowo Kinihun VI.

Kinihun yii ni wọn ta ajọ LASSESSO lolobo pe o wa ni agbegbe Muri Okunola ni Victoria Island l'Eko.

Bawo ni ọrọ kinihun yii ṣe jẹ? Ó di dandan kí ará India yìí sọ ìdí tó fi ń sìn kìnìhún- Egbeyemi

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÓ di dandan kí ará India yìí sọ ìdí tó fi ń sìn kìnìhún- Egbeyemi

Ọgbẹni Yinka jẹ ko di mimọ pe ẹni ti awọn kọkọ fi ọwọ ofin mu ni arakunrin Hausa to n ṣọ ile ti Kinihun wa ọhun to si kẹnu bọ ọrọ fun awọn lẹyin ti wọn bi i leere pe ki lode ti ko fọ̀hun fawọ́n tọrọ kan pe oun n ṣọ Kinihun ninu ile.

Ọgbẹni Yinka sọ fun BBC Yoruba pe aṣọgba ile naa lo fidi rẹ mulẹ fun awọn to jẹ ki wọn mọ pe lati orilẹede Cameroon ni ọga oun to jẹ ara ilẹ India ti ru Kinihun yii wọle wa si Naijiria.

Lara iwadii ti ajọ LASSESSO ṣe, wọn ri i pe, arakunrin India yii n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ kan, Sterlin Global. Ileeṣẹ yii kan naa lo gba ile fun arakunrin naa.

Ẹwẹ, a gbọ pe lati inu oṣu keji ọdun ni ileeṣẹ ti gba ile ṣugbọn arakunrin naa kii fibẹẹ gbe ile ọhun titi di asiko yii.

Aṣọgba ile naa sọ fun ajọ LASSESSO pe ẹnu ẹnu ni ga oun fi ni oun fẹ tun ile naa ṣe daadaa ko le dun gbe ṣugbọn ko tii tun un ṣe di oni.

Wọn ni nigbati ọrọ kan eti onile ni onile kọwe ranṣẹ si ọdọ awọn ti wọn si bẹrẹ si ni gbe igbesẹ.

Ni kete ti wọn yin oogun akuniloorun meji to lagbara lu Kinihun yii to si moorun lọ ni wọ́n gbe e kuro nile naa ti wọn si gbe e lọ si ọgba ti wọn n ko ẹranko inu igbo si.

Ọgbẹni Yinka ni awọn gba ipe kan nigba ti wọn de ọfiisi wọn ti ni naa si ni oun n bọ pẹlu olowo Kinihun yii lati wa ba wọn ni gbolohun.

"Lọ́gán ti a ba ti ba ara India ọhun ni gbolohun tan la o gbe ẹjọ naa kuro lọdọ tiwa sọwọ awọn agbofinro tọrọ̀ kàn".