A jọ ṣe ìyàwó pọ̀, a jọ bímọ ní ọjọ́ kan náà, a tún jọ máa ń ṣàìsàn pọ̀ ni
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹ̀mí kan náà ló n darí ìrìnàjò wa táa fi jọ kọ́lé papọ̀- Ìbejì

Lati oṣu mẹwaa di ẹni ọdun marundinlọgọta lati jọ wa papọ gẹgẹ bii ẹni kan ninu ara meji- Ibeji

Arabinrin Taiwo Olawoyin ati Arabinrin kehinde Adeniran ni awọn ibeji ti ko sẹni to le ri aarin wọn lẹyin ọdun marundinlọgọta ti wọn ti lo loke eepẹ.

Nitootọ ni awọn ibeji maa n jọ ara wọn nile aye ṣugbọn ti awọn wooli Olorun meji yii yatọ.

Àkọlé àwòrán Ko si ẹni to le ya wa layelaye

Awọn ọkọ awọn mejeeji to jẹ pasitọ ijọ Olorun naa ni awọn ti gba wọn papọ ati pe ọrọ awọn jọ ye ara wọn ni

Ojo kan naa ni wọn jọ ṣe igbeyawo, ọjọ kan naa ni wọn tun jọ bimọ laiki n ṣe pẹlu iṣẹ abẹ.

Àkọlé àwòrán A jijọ gbagbọ ninu Olorun ni lati igab ewe wa

Awọn mejeeji ni lati inu oyun ni wọn ti sọ fun iya wọn pe iṣẹ Oluwa ni wọn maa ṣe.

Koda, wọn ni ti ọkan ninu wọn ba ṣaisan, awọn mejeeji ni wọn jọ maa lo oogun!

Àkọlé àwòrán Won jo n sin Olorun ninu iṣẹ iranṣẹ pẹlu awọn ọkọ wọn ni