Constituency office: Kí ni pàtàkì ọ́fíìsì agbègbè fún aṣòfin?

Aarẹ Ile asofin agba pẹlu asofin kan n sọrọ Image copyright Nigeria senate

Njẹ o mọ ẹni ti o n ṣoju fun ẹkun idibo agbegbe rẹ ni ile aṣofin apapọ bi? Yala gẹgẹ bii sẹnetọ tabi aṣojuṣofin?

Lẹyin ti idibo ba ti waye tawọn oloṣelu to n du ipo gbogbo, ninu eyi ti awọn ipo ile aṣofin apapọ pẹlu wa ni wọn maa n dawati.

Opọ gba pe ti polongo ibo wọn pẹlu oniruuru agbọ-pọnula ileri fun araalu ba ti pari, ọpọ igba ni awọn oloṣelu kii boju wo ẹyin mọ titi di igba ti ọdun mẹrin miran ba ti pe ti wọn tun nilo ibo araalu.

Nitori idi eyi kii ṣe kayeefi pe lọpọ igba ati kaakiri ipinlẹ lorilẹ-ede Naijiria ni awọn araalu kii mọ ibi ti wọn lee wa awọn aṣoju wọn si.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ofin laa kalẹ pe awọn aṣofin yoo ni ileeṣẹ agbegbe lawọn ẹkun idibo wọn sibẹ ọpọ ni ko mọ ibi ti awọn ileeṣẹ wọnyii wa.

Pabanbari rẹ tilẹ ni pe ọpọ awọn aṣofin ni ko tilẹ ni awọn ileeṣẹ wọnyii.

Ki gan an ni pataki ileeṣẹ agbegbe (constituency office) fun aṣofin?

Pataki ileeṣẹ agbegbe ni lati maa gbọ aroye ati ẹdun ọkan awọn eeyan agbegbe ti irufẹ aṣofin bẹẹ n ṣoju fun.

Ọfiisi to yẹ ko ṣi silẹ gbaragada fun tẹrutọmọ ni.

Eyi tumọ si pe kii ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Sẹnetọ tabi aṣoju-ṣofin naa nikan lo lẹtọ lati maa wa sibẹ pẹlu ẹdun wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Aids Day: Wo bí kòkòrò ààrùn HIV se bẹ̀rẹ̀ lágbàyé!

Koda lati ibẹ lo yẹ ki awọn ara ilu ti maa mọ ipele to kan ninu iṣẹ akanṣe ti aṣoju wọn n gbero atiṣe fun ilu rẹ

Bakan naa lo yẹ ki wọn mọ bo ṣe n na owo ilu to n gba ni Abuja fun idagbasoke agbegbe ọhun ti wọn ba ti wọ inu ọọfiisi yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA

Related Topics